Awa kọ la yinbọn pa awọn ọdọ ni Lẹkki-Ileeṣẹ Ologun

Ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti sọ pe ko soootọ ninu ohun ti aọn kan n sọ kiri pe awọn lawọn ran awọn ṣọja lọ si Lẹkki, niluu Eko lati lọọ yinbọn pa awọn ọdọ ti wọn n fẹhonu han lodi si SARS, eyi to waye lalẹ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ninu iroyin kan ti wọn gbe si ori ẹrọ ayelujara wọn ni wọn ti ni iroyin ofege lasan ti ko lẹsẹ nilẹ ni awọn eeyan n gbe kiri pe awọn lawọn yinbọn pa awọn ọdọ ni Lẹkki.

Epe nla ni ọpọ awọn to ka ohun ti wọn sọ yii n gbe wọn ṣẹ. Ibeere ti wọn si n beere ni pe ṣe anjọnnu lo pa awọn ọmọ yii. Nigba ti eri loriṣiiriṣii fi han pe awọn ni wọn ṣina ibọn fun awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn n ṣewọde jẹẹjẹ wọn.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

2023: Ẹgbẹ TOTT rọ Tinubu atawọn oludije yooku lati panu pọ gbe Ọṣinbajo kalẹ

Ọrẹoluwa Adedeji Ẹgbẹ kan, The Ọsinbajo Think Tank (TOTT), ti parọwa si aṣaaju ẹgbẹ oṣelu …

One comment

  1. Tobaje awọn won Oni sọpe awọn ni.ani awọn ọdọ yise suuru na

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: