Awa kọ la yinbọn pa Jumọkẹ, ọmọbinrin to ku lasiko iwọde l’Ọjọta- Ileeṣẹ ọlọpaa

Faith Adebọla, Eko

Latari ẹsun ti wọn fi kan wọn pe ibọn ọkan lara awọn oṣiṣẹ wọn lo ṣeku pa Jumọkẹ, ọmọọdun mẹrinla, kan lasiko rogbodiyan to waye nibi iwọde ‘Yoruba Nation’ lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide yii, l’Ọjọta, nipinlẹ Eko, ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe irọ ni wọn n pa m’awọn o, awọn kọ lawọn yinbọn ọhun.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ naa, CSP Olumuyiwa Adejọbi, fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, o ni, “Ọrọ nipa ẹsun ṣiṣẹkupa ọmọ ọdun mẹrinla kan nibi iwọde Oodua l’Ekoo, wọn ni awọn to fẹẹ da họu-họu ati ifoya silẹ laarin ọlọpaa ati araalu lo wa nidii ẹsun ti wọn fi kan wọn ọhun.’’

Wọn ni loootọ lawọn yinbọn nibi iwọde Mega Rally yii, lati fi le awọn oluwọde atawọn janduku ti wọn fẹẹ dana ijangbọn silẹ kuro, ṣugbọn ko si ọta gidi kan ninu awọn ibọn tawọn n yin, oke si lawọn n yin in si.

Wọn ni loootọ lawọn ri oku ọmọbinrin ti wọn n sọ yii lọọọkan nibi tawọn duro si, wọn lẹyin ileepo MRS to wa l’Ọjọta loku naa wa, o si ti wa nibẹ kawọn too de agbegbe naa fun iṣẹ aabo tawọn ba wa, ibi tawọn duro si jinna si oku ti wọn fẹẹ ti ọran rẹ m’awọn lọrun yii, ẹjẹ to si wa lara aṣọ oku naa ki i ṣe ẹjẹ ṣoroṣoro, ẹjẹ to to gbẹ ni, to fihan pe oloogbe naa ti ku tipẹ.

Adejọbi tun ṣalaye pe nigba tawọn yẹ oku naa wo daadaa, awọn ri i pe nnkan ija bii ọbẹ tabi aṣooro lo dọgbẹ si i lara, ki i ṣe apa ọta ibọn rara.

“Lori irọ niroyin yii, ki i ṣe ootọ rara, a rọ ẹyin araalu lati ma ṣe gba a gbọ, a fẹ kẹyin eeyan maa ba igbokegbodo yin lọ lai mikan, a si ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣeku pa oloogbe ti wọn n sọrọ ẹ yii.”

Bẹẹ ni atẹjade naa sọ.

Sibẹ, iroyin yii ṣi n lọ kaakiri ẹrọ ayelujara, ọpọ eeyan lo si gbagbọ pe awọn ọlọpaa lo fibọn gbẹmi ọmọbinrin naa. Fidio kan to jade lẹyin iṣẹlẹ yii tun ṣafihan mọlẹbi ọmọbinrin ọhun to n barajẹ fun bi wọn ṣe da ẹmi ọmọ naa legbodo lai rotẹlẹ.

ALAROYE gbọ pe ṣọọbu ni ọmọbinrin yii wa to ti n to miniraasi ti ọta ibọ si lọọ ba a nibẹ. Oju-ẹsẹ naa lo si ku

Leave a Reply