Awa la ṣeeṣi yinbọn si abule ti eeyan mẹwaa ti ku, tọpọ fara pa, nipinlẹ Yobe- Ileeṣẹ ologun ofurufu

Jọkẹ Amọri

Ileeṣẹ ologun ofurufu ilẹ wa ti jẹwọ pe loootọ lawọn ṣeeṣi yinbọn si abule kan ti wọn n pe ni Abule Buhari, nijọba ibilẹ Yanusari, to wa ni ipinlẹ Yobe, nibi ti eeyan mẹwaa ti ku, ti awọn to le ni ogun fara pa yanna yanna ti wọn si wa lọsibitu ti wọn ti n gba itọju.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii naa ni ibọn deede n dun lakọ lakọ ni abule naa, ti ọrọ si di bo o lọ o yago. Ki awọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, eeyan mẹwaa ti ku, ti ọpọ si fara pa yannayanna.

Ileeṣẹ ologun ilẹ wa lawọn to mọ nipa iṣẹlẹ yii naka rẹ si, ṣugbọn awọn eeyan naa ni awọn ko mọ ohunkohun nipa rẹ.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni wọn too jẹwọ pe loootọ lawọn ṣeeṣi yinbọn si abule naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ologun ofurufu, Edward Gabkwet, lo ṣalaye pe awọn ikọ ọmọ ogun ofurufu lọ si agbegbe kan ti wọn n pe ni Kamadougou River line, ni ipinlẹ Yobe, lati dọdẹ awọn Boko Haram ati ISIS kan, nitori awọn gbọ pe wọn n jẹ̀ sibẹ, bẹẹ ni awọn kofiri awọn eeyan naa ni awọn agbegbe yii to paala pẹlu ipinlẹ Niger.

O ni nitori ibẹ jẹ ibuba awọn Boko Haram lawọn fi fi da ibọn bo agbegbe naa pẹlu ẹsun ti awọn eeyan ti n mu wa pe ibuba awọn afẹmiṣofo yii ni.

Ṣugbọn o ni o ṣe ni laaaanu pe awọn pada gbọ pe ibọn naa ṣeeṣi ba awọn araaalu ti aọn kan ku, ti ọpọ si fara pa.

Edward ni ohun to mu ki awọn kọkọ sọ pe awọn ko mọ nipa iṣẹlẹ naa ni nigba ti wọn n sọ pe bọmbu ni wọn yin, nitori awọn ko gbe bọmbu lọ sibẹ.

O ni wọn ti gbe igbimọ oluwadii dide lati ṣewadii to tọ lori iṣẹlẹ naa.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni iṣẹlẹ naa waye, nibi tawọn ologun oju ofurufu ti ṣina ibọn bolẹ ni Abule Buhari, nipinlẹ Yobe, ti eeyan mẹwaa ku, ti ọpọ si farapa yannayanna.

Leave a Reply