Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ni itẹsiwaju igbẹjọ iku akẹkọọ Fasiti Ifẹ to ku si otẹẹli Hilton, loṣu Kọkanla, ọdun to kọja, iyẹn Timothy Adegoke, oṣiṣẹ wolewole kan, Adejumọ Fatai Adebọwale, ẹni to n ṣiṣẹ pẹlu ijọba ibilẹ Aarin-Gbungbun Ifẹ, ni wọn gbe wa si kootu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Ọkunrin naa ṣalaye pe ojuṣẹ akọkọ ti oun ni gẹgẹ bii oṣiṣẹ wolewole ni lati dena ohunkohun to le fa itankalẹ arun buburu kaakiri agbegbe, ọdun kọkanlelọgbọn ti oun si ti wa lẹnu iṣẹ naa niyi.
Adejumọ ṣalaye pe “Lọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ni mo gba ipe kan latọdọ DPO ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Mọọrẹ, Ileefẹ. O sọ fun mi pe oku kan wa loju-ọna Ẹdẹ si Ifẹ, mo beere pe ṣe wọn ti sọ fun alaga kansu wa, Ọnarebu Jacob Elugbaju, o ni bẹẹ ni.
“N ko lanfaani lati ba alaga sọrọ lọjọ naa, ṣugbọn lọjọ keji ti mo pe alaga lori foonu, o ni oun ti gbọ nipa rẹ. Nigba ti mo de ọfiisi, iyẹn lọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, ọdun to kọja, mo ti ba lẹta ti DPO yii kọ si alaga kansu lori ọrọ oku naa.
“Bayii la bẹrẹ igbesẹ lori lẹta yẹn, oṣiṣẹ kansu bii mẹjọ ni lẹta naa si gba ori tabili wọn kọja ko too di pe wọn buwọ lu u. Wọn si fun mi ni ẹgbẹrun lọna ogun Naira lati fi ṣeto awọn to maa sinku yẹn.
“Nigba ti a debi ti DPO juwe fun wa, mo fi foonu android mi ya fọto ipo ti a ba oku yẹn. O ti jẹra pupọ. Inu paali kan ni wọn gbe e si, wọn si fi okun yi i ki wọn too ju u sinu paali yẹn. A ko rina ri aṣọ ti o wọ, ṣugbọn kekere ti mo ri nibẹ, sẹẹti pupa lo wọ soke.
“Pẹlu bo ṣe ti jẹra (decay) yẹn, a ko le gbe e lọ sibi to jinna, idi niyẹn ti a fi pinnu lati gbẹ koto sẹgbẹẹ rẹ, a si gbe e sinu ẹ. Gbogbo igbesẹ wa ni mo ya fọto ẹ, bakan naa la si fumigeeti gbogbo agbegbe yẹn, ṣaaju, lasiko ati lẹyin ti a n sinku yẹn lọwọ.
“Aago meji ọsan ọjọ yẹn la pari gbogbo nnkan ti a ṣe nibẹ, bi a si ti ṣetan ni mo fi gbogbo fọto ti mo fi foonu mi ya ṣọwọ si wasaapu alaga kansu wa, Ọnarebu Eluyẹra.
“N ko gbọ nnkan kan nipa oku yii mọ titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun to kọja, nigba ti DPO Mọọrẹ pe mi pe awọn ọlọpaa kan lati Oṣogbo fẹẹ ri mi lọfiisi rẹ fun alaye nipa oku ti a sin. Mo lọ sibẹ, mo si ṣalaye gbogbo nnkan ti mo mọ, mo si fun wọn ni fọto.
“Nigba to tun di ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun to kọja, n ko si lọfiisi, wọn si sọ fun mi pe awọn ọlọpaa kan beere mi lati Abuja, wọn si sọ pe ki n kọja si ẹka ọtẹlẹmuyẹ niluu Oṣogbo. Mo lọ sibẹ, mo ṣalaye ohun ti mo mọ, mo si ko fọto fun wọn ati iwe aṣẹ ti mo gba ni kansu lati sinku yẹn.”
Gbogbo awọn agbẹjọro awọn olujẹjọ ni wọn beere ibeere lọwọ Adejumọ, o si da wọn lohun. Lẹyin eyi ni adajọ kootu naa, Onidaajọ Adebọla Adepele-Ojo, sun igbẹjọ siwaju di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.