Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti ke si gbogbo awọn ori-ade, awọn agbaagba pẹlu awọn lookọ-lookọ nilẹ Yoruba lati lọọ ba Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ pe ko tu ajijagbara nni, Sunday Adeyẹmọ Igboho, silẹ.
Ọba Akanbi, ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, fi sita, sọ pe itusilẹ Sunday Igboho yoo tubọ fi ẹsẹ iṣọkan mulẹ lorileede Naijiria.
Oluwoo parọwa si gbogbo awọn lọba lọba lati ṣa gbogbo ipa wọn lati le tu ọmọ wọn, Sunday Igboho, silẹ.
Bakan naa lo ke si Aarẹ Buhari lati bọwọ fun awọn ọba-ilẹ Yoruba ati awọn lookọlookọ nipa ṣiṣe nnkan ti wọn ba fẹ lori ọrọ Igboho nitori eleyii yoo tubọ mu ki awọn ọmọ Yoruba nile ati lẹyin odi bọwọ fun iṣọkan Naijiria.
Ọba Akanbi rọ ijọba apapọ lati ba ijọba orileede Benin Republic sọrọ, ki wọn si da Sunday Igboho pada si orileede yii lalaafia lai ba a ṣẹjọ mọ, eleyii yoo si jẹ koriya fun awọn ọmọ ilẹ Yoruba tootọ.
Oluwoo sọ siwaju pe, “Awuyewuye to n lọ lori bi Sunday Igboho ṣe wa lọgba ẹwọn yẹn le wa sopin ti awọn ori-ade ati awọn lookọlookọ nilẹ Yoruba ba dide tọ Aarẹ Buhari lọ.
“Ọmọ wa ni Sunday Igboho, o ti ṣe awọn aṣiṣe kan nipa fifi agbara wa ominira ilẹ Yoruba. Ọwọ to fi mu ọrọ yẹn lo dabaru gbogbo nnkan.
“Amọ ṣa, ki gbogbo wa ṣiṣẹ papọ lati gba Igboho silẹ nipa titọ Aarẹ lọ, ka si jọ sọrọ lori ẹ. Tijọba apapọ naa ba ṣe eleyii fun wa, yoo jẹ ki iṣọkan tubọ nipọn si i lorileede yii.
“Ijọba apapọ nikan lo le ba wa gba itusilẹ Igboho, a oo si gboriyin fun wọn ti wọn ba gbe igbesẹ agba ati ti iṣọkan yii”
Ọba Akanbi tun ke si gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati tubọ maa wa iṣọkan ati idagbasoke ilẹ wa.