Awada lasan ni bi awọn Mayetti Allah ba lawọn yoo koju ija si Yoruba-Gani Adams

Aderohunmu Kazeem

Latẹnu akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kẹhinde Akinrẹmi, ni Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Ọtunba Gani Adams, ti kede pe awada lasan ni bi awọn ẹya Hausa l’Oke-Ọya ba dan an wo pe awọn yoo kọju ija si Yoruba, o ni ala ti ko ni i le ṣẹ ni, nitori gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un.

Ni Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii, lo sọrọ naa lati da ẹgbẹ awọn Hausa ti wọn n pe ni Arewa ati Miyetti Allah to jẹ tawọn Fulani loun pẹlu ihalẹ ti wọn n ṣe pe awọn yoo gbẹsan ikọlu ti awọn ọdọ ilu Igangan ṣe si awọn Fulani darandaran niluu naa.

Aarẹ kilọ pe bi wọn ba fi le kọju ija si awọn eeyan Ibarapa tabi awọn ara ipinlẹ Ondo ti wọn ni awọn ko fẹ wọn nipinlẹ naa mọ, wahala kekere kọ ni igbesẹ bẹẹ yoo da silẹ nilẹ wa.

O ni igbesẹ ti awọn eeyan ipinlẹ naa gbe wa ni ibamu pẹlu awọn ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe wọn pẹlu bi awọn Fulani darandaran ṣe n ji awọn eeyan wọn gbe, ti wọn n pa wọn, ti wọn si n ṣe wọn leṣe.

Iba waa ṣekilọ fun awọn eeyan Oke-Ọya naa pe ki wọn yee kọrin tabi lu ilu ogun, nitori Yoruba ko ni i sa rara, gbogbo agbara to ba si wa ni ikapa wọn ni wọn yoo ṣa lati daabo bo ilẹ wọn lọwọ ikọlu awọn Fulani.

Leave a Reply