Jide Alabi
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti gbe awakọ BRT kan, Bohan Abiọdun, lọ sile-ẹjọ Majireeti kan niluu Ọgba, l’Ekoo.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ṣeku pa ọlọkada kan atawọn ero meji to gbe lọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni deede aago mẹrin owurọ. Aduugbo kan ti wọn pe ni Ile-Igbo, lagbegbe Abule-Ẹgba, niluu Eko, ni wọn lo ti kọ lu wọn, nigba ti ọlọkada ọhun gba ojuna BRT, ati pe ko tan ina ọkada ẹ paapaa nigba ti iṣẹlẹ ọhun waye.
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe ọlọkada yii ku pẹlu ọkan lara awọn ero to gbe, ti wọn sì sare gbe ẹni kẹta lọ si ọsibitu fun itọju.
Ẹsun onikoko meji ni wọn ka si awakọ BRT yii lẹsẹ. Wọn lo wa ọkọ akero ọhun ni iwakuwa laarin ilu, bẹẹ lo tun fi mọto paayan danu.
Niwaju Adajọ O.A Ọlayinka, ni awakọ yii ti wọn pe lẹni ọdun mejidinlaaadọta ti sọ pe oun ko jẹbi, bọ tilẹ jẹ pe olupẹjọ, Ezekiel Ayọrinde, sọ pe eeyan mẹta lo ṣeku pa, bẹẹ lọ lodi si ofin irinna ọkọ ipinlẹ Eko, tọdun 2018.
Adajọ O.A. Olayinka ti gba lati fun un ni beeli pẹlu oniduuro meji pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin-o-din-aadọta naira (N750,000).
Ọgbọn ọjọ, oṣu yii, ni ẹjọ ọhun yoo maa tẹ siwaju.