Awakọ ẹru ko sodo l’Ekoo, lojuẹsẹ lo ku

Aderounmu Kazeem

Pẹlu ibanujẹ lawọn mọlebi kan fi gba oku ọmọ wọn lọwọ awọn oṣiṣẹ ijọba lẹyin ti mọto ẹ to wa ko sodo, toun naa si ku lojuẹsẹ

Adugbo kan to n jẹ Owode Elede, lojuna Ikorodu, niṣẹlẹ buruku ọhun ti waye lana-an. Mọto akẹru kan lawọn eeyan ri to ti ja sodo kan lagbegbe naa, ti ẹni to wa a si ti ku patapata.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹfa ku iṣẹju mẹẹdogun nijanba ọhun waye, ati pe dẹrẹba to wa a nikan lo wa ninu ọkọ ọhun.

Ọga agba  fun iṣẹlẹ pajawiri l’Ekoo, Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu, sọ pe, “Loju-ẹsẹ ta a gbọ si iṣẹlẹ ọhun ni awọn oṣiṣe wa ti debẹ, niṣe la ba mọto akẹru ọhun ninu odo to wa ni Owode-Elede lojuna Ikorodu. Dẹrẹba to wa a nikan la ba ninu ẹ, o si ti ku. Iwakuwa ni wọn sọ pe o fa ijanba ọhun, bẹẹ lẹru to ko paapaa ti pọju.”

Ọsanyintolu fi kun un pe lẹsẹkẹsẹ lawọn ti gbe oku ẹ fawọn mọlẹbi ni kete ti wọn ti yọju sibi iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply