Awakọ pa oṣiṣẹ LASTMA l’Ekoo

Jide Alabi

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii ni ẹṣọ agbofinro to n dari ọkọ, iyẹn LASTMA pade iku ojiji lagbegbe Mile 12, niluu Eko.

Ninu ọrọ ọga agba fun ileeṣẹ ọhun, Ẹnjinnia Ọlajide Oduyọye, lo ti sọ pe Samson Ọlawale Akinmade ni orukọ oṣiṣẹ LASTMA to pade iku ojiji ọhun.

Aarọ kutu Ọjọruu lo ni ọkunrin naa kagbako iku nibi to ti n dari ọkọ ti bọọsi Opel kan ti nọmba ẹ jẹ AAA 74 GG ti kọ lu u, to si pa a loju-ẹsẹ.

Adugbo kan to n je Demurin, lati maa lọ si Mile 12, niṣẹlẹ buruku yii ti ṣẹlẹ, nibi ti ọkunrin naa ti n dari ọkọ. Ori ni wọn sọ pe o fi lulẹ, to si tun fi ara pa pẹlu.

Ọsibitu Yunifasiti LASU ni wọn sare gbe e lọ, nibẹ naa ni wọn ti jẹ ki wọn mọ pe o ti ku.

Ọga agba fun ajọ LASTMA ti ṣapejuwe ọkunrin yii bii ẹni to maa n jara mọ iṣẹ ẹ daadaa.

O ni, “O ṣe ni laaanu pe ọkunrin awakọ oniwakuwa yii kan fi tiẹ ba ti ẹni ẹlẹni jẹ ni. O ti ko awọn ẹbi oloogbe yii si wahala bayii, bẹẹ ni ko jẹ ki Samson paapaa ri ile aye gbe mọ. O tun fi tiẹ ko ba awa naa nileeṣẹ wa, nitori ọkan ninu awọn oṣiṣẹ wa to mu iṣẹ ẹ bii iṣẹ ni.

 

Leave a Reply