Awakọ pa ọlọkada sori afara niluu Ilọrin 

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Ọlọkada kan ti ko ti i sẹni to mọ orukọ rẹ pade iku ojiji lọjọ Ẹti, Furaidee, lẹyin ti awakọ ayọkẹlẹ kan kọ lu u lori afara to wa ni Post Office, niluu Ilọrin, to si sa lọ.

Ijamba ọhun to ṣẹlẹ ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ lawọn to ṣoju wọn ni ere asapajude lo fa a.

Ọlọkada ọhun to gbe ero sẹyin ni wọn loun pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ naa fori sọ ara wọn, loju ẹsẹ ni ọkunrin naa si ku, ṣugbọn ẹni to gbe sẹyin farapa yannayanna.

Awọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto irinna ọkọ nipinlẹ Kwara, KWARTMA, lo lọọ gbe oku ọlọkada naa ati ẹni to farapa lọ sileewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, nibi to ti n gba itọju.

Leave a Reply