Awọn alaga kansu ipinlẹ Ọyọ to pe Makinde lẹjọ fidi-rẹmi ni kootu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ti fi aṣẹ ijọba le awọn alaga kansu ipinlẹ Ọyọ kuro nipo bii ẹni le ewurẹ, igbiyanju awọn eeyan naa lati pada sipo wọn ti fori ṣapọn. Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe fidi-rẹmi ni kootu lonii ninu ẹjọ ti wọn pe ta ko igbesẹ gomina yii.

Awọn eeyan wọnyii lawọn araalu dibo yan sipo alaga kansu kaakiri awọn ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) atawọn ijọba ibilẹ onidagbasoke maraadundinlogoji (35) to wa ni ipinlẹ Ọyọ lasiko iṣejọba gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Oloogbe Abiọla Ajimọbi. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Party (APC), ni gbogbo wọn.

Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2019, ti wọn bura fun Makinde gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọyọ lọkunrin naa yẹ aga mọ wọn nidii, to si fi alaga afún-n-ṣọ́ ta a mọ si kíátekà rọpo wọn lẹyin oṣu bii meji sigba naa.

Awọn ti gomina yọ nipo yii, ti wọn tun jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn alaga kansu nilẹ yii, iyẹn Association of Local Governments of Nigeria (ALGON), eyi ti Ọmọọba Abass Alẹsinlọyẹ jẹ alaga wọn, ti kọ faake kọri, wọn ni ko si baba nla ẹni to le le awọn kuro nipo ti awọn araalu dibo yan awọn si.

Ẹni to n ba wọn fa a paapaa ko ba wọn mu un ni kekere. Ọrọ ọhun si dija rẹpẹtẹ laarin awọn alaga afún-n-ṣọ́ ti Gomina Makinde fi rọpo wọn pẹlu awọn alaga ti wọn yẹ aga iṣakoso mọ nidii yii to bẹẹ to jẹ pe bi wọn ṣe n tori ẹ paayan ni wọn n ṣe ara wọn leṣe. Lẹyin naa lawọn ọmọ ẹgbẹ ALGON yii, labẹ idari Ọmọọba Abass Alẹṣinlọyẹ ti i ṣe alaga wọn, gba kootu lọ, wọn ni kile-ẹjọ fagi le igbesẹ gomina naa patapata, ki wọn si da onikaluku awọn pada sipo alaga ijọba ibilẹ awọn.

Awijare wọn ni pe ofin ko fun gomina lagbara lati yọ awọn nipo nigba ti ki i ṣe oun lo fi wọn sipo naa, to jẹ pe awọn araalu lo dibo yan awọn gẹgẹ bii alaga kansu.Wọn ni ọpọlọpọ gomina lo ti gbe iru igbesẹ bẹẹ sẹyin ṣugbọn ti ile-ẹjọ fagi le e, ti wọn si paṣẹ pe ki awọn da awọn alaga kansu naa pada sipo wọn.

Ṣugbọn laaarọ yii (Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keje, ọdun 2020), nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ijọba apapọ to wa laduugbo Ring Road, n’Ibadan, dajọ pe ki awọn alaga kansu ti wọn rọ loye yii jokoo wọn jẹẹ sile koowa wọn

Adajọ kootu naa, Onidaajọ Justice Haruna Tsammani, sọ pe awọn olupẹjọ wọnyi ko ni ẹri to munadoko to lati fi han pe ko tọna fun Gomina Makinde lati le awọn kuro nipo gẹgẹ bii alaga kansu.

Leave a Reply