Awọn dokita lugbadi arun Korona lọsibitu ijọba n’Ibadan, ni wọn ba ti i pa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Itankalẹ kokoro arun Korona tun bọna mi-in yọ lanaa pẹlu bi awọn dokita, nọọsi atawọn oṣiṣẹ ileewosan ijọba Jericho Specialist Hospital, n’Ibadan, ṣe fara kaaṣa ajakalẹ arun naa.

Alamoojuto fun awọn iṣẹlẹ to ba ni i ṣe pẹlu ọrọ ajakalẹ arun nipinlẹ Ọyọ, Dokita Taiwo Ladipọ, lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin lanaa. O ni awọn kan ninu awọn dokita atawọn nọọsi to n tọju awọn alaisan nileewosan Jericho ti lugbadi arun Korona o.

Ba a ṣe n wi yii, awọn dokita atawọn nọọsi tọrọ ọhun kan ti wa ni ifarapamọ bayii, wọn si ti ti abala ileewosan ọhun kan pa.

Gẹgẹ bo ṣe fidi ẹ mulẹ, Dokita Ladipọ ṣalaye pe “Ọkan ninu awọn alarun Korona la n tọju nileewosan yii ti kokoro naa fi ran awọn dokita to n tọju ẹ pẹlu awọn nọọsi to ti ni nnkan kan tabi ekeji i ṣe pẹlu ẹni yẹn.

“Bi esi ayẹwo yẹn ṣe jade, to fidi ẹ mulẹ pe awọn dokita atawọn nọọsi yẹn ti fara ko kokoro arun Korona la ti ti ẹka ti wọn ti n ṣiṣẹ pa ko ma di pe ajakalẹ arun yẹn maa ran de awọn ẹka yooku naa.’’

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: