Awọn janduku ya wọ teṣan ọlọpaa n’Ibadan, wọn yinbọn pa kọburu kan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Aṣa fi òròmọdìẹ silẹ, àkùkọ atawọn àgbébọ̀ adiẹ nla nla lo ku to ń gbé n’Ibadan bayii pẹlu bi awọn janduku ṣe fi awọn alailagbara silẹ, to jẹ pe awọn ọlọpaa ni wọn n lọọ yinbọn pa bayii.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020 yii, niṣẹlẹ kayeefi ọhun waye, nigba ti awọn janduku agbebọn kan lọọ ka awọn agbofinro mọ agọ ọlọpaa to wa laduugbo Ikọlaba, n’Ibadan, ti wọn si yinbọn pa ọlọpaa kan, omi-in si fara pa yannayanna.

Gẹgẹ bi awọn olugbe adugbo ọhun ṣe sọ, bi awọn ẹruuku ọhun ṣe de iwaju teṣan naa ni wọn bẹrẹ si i yinbọn leralera, ti awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ lasiko naa si bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn nitori ti iṣẹlẹ ọhun ba wọn lojiji.

Amọ ṣa, ori ko ṣe bẹẹ ko ọkan ninu awọn kọburu ọlọpaa teṣan naa to n jẹ Dada Christopher yọ pẹlu bi ibọn ṣe ba a, to si j’Ọlọrun nipe loju ẹsẹ. Bẹẹ ni ripẹtọ ọlọpaa kan fara pa.

Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii, ẹnikẹni ko ti i mọ awọn ogboju ọdaran to huwa òdóró wọnyi ati idi ti wọn ṣe huwa ika naa.

Ṣugbọn agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, ti sọ pe ki i ṣe agọ ọlọpaa lawọn ọdaran naa kọ lu, wọn kan yinbọn mọ awọn agbofinro meji kan niwaju agọ ọlọpaa ọhun ni.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, SP Fadeyi ṣalaye pe “ki i ṣe teṣan ọlọpaa lawọn janduku kọ lu. Awọn ọlọpaa teṣan Ikọlaba ni wọn duro siwaju teṣan yẹn nigba ti awọn ọmọ iṣọta wọnyẹn wa mọto kọja mọ wọn lara, ti wọn si yinbọn fun wọn lati inu mọto yẹn lai duro.

“Eyi to jẹ kọburu ninu awọn ọlọpaa yẹn ku. Eyi ripẹtọ to fara pa ṣi n gbatọju nileewosan titi di ba a ṣe n wi yii.”

Agbẹnusọ awọn agbofinro yii sọ pe bi ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ yii lo ti ran awọn ikọ ọlọpaa loriṣiiriṣii jade lati ṣawari awọn ọdaran naa.

 

Leave a Reply