Awọn ọmọ ita gbajọba n’Ibadan, wọn fọ ọpọlọpọ ṣọọbu lọsan-an gangan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bii ilu ti ko lofin ati adari n’Ibadan ri lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pẹlu bi awọn janduku ṣe gbajọba adugbo Gbaremu Idi-Obi, nigboro ilu naa, ti wọn si bẹrẹ si i ja awọn ṣọọbu oniṣọọbu jale laago mejila ọsan gangan.

Lati okeere lawọn ontaja ti wọn ja lole ọhun ti n woran bi wọn ṣe n ji wọn lẹru ko lẹyin ti awọn tọọgi naa ti fi apola igi le wọn jade ni ṣọọbu wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ija lo bẹ silẹ laarin awọn ọmọ iṣọta agbegbe naa ti wọn fi bẹrẹ si i fi apola igi le ara wọn kiri. Nibi ti awọn ontaja to wa nibẹ si ti n sa asala fun ẹmi wọn lawọn janduku ọhun ti lo oorẹ-ọfẹ naa lati jale.

Awọn Amọtẹkun, iyẹn ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba, ẹka tipinlẹ Ọyọ, la gbọ pe wọn lọ sibẹ lati tu awọn adaluru ọhun ka, ti awọn ara agbegbe naa fi le fẹ̀dọ̀ lérí òróǹro.

Nigba ti akọroyin wa pe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni wọn ko ti i fi ọrọ naa to awọn leti.

Leave a Reply