Awọn ọlọpaa Ghana da ọmọ Barrista lare, wọn ni ko mọ nipa iku ọrẹ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Latari iroyin to gbode kan lori Balogun(Barry Jhay) ọmọ Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister, ti wọn lo pa ọrẹ ẹ, to tun jẹ ọga ẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ, iyẹn Babatunde Oyerinde Abiọdun,( Kashy Godson) ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Ghana ti yanju awuyewuye naa. Wọn ni ọmọ Barrista ko mọ nnkan kan nipa iku ọrẹ ẹ naa, wọn ni oloogbe yii lo pa ara ẹ, ẹnikan ko pa a.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta yii, ni ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Ghana fi atẹjade kan sita lati tan imọlẹ si ọrọ yii. Ohun ti wọn sọ sibẹ ni pe Kashy, ọdọmọde olowo to ni ileeṣẹ Cash Nation, lo mọ-ọn-mọ ja bọ lati ori oke otẹẹli alaja mẹrin to wa. Ori lo fi gbalẹ bo ṣe ja bọ, ẹsẹkẹsẹ naa lo si ku bi wọn ṣe wi.

Lati tubọ fidi ẹri wọn mulẹ lori iku Kashy, awọn ọlọpaa naa sọ pe yatọ si awọn ẹlẹrii ti Kashy toju wọn ja bọ, kamẹra to wa ni otẹẹli Beauford Ridge, Adabraka , to de si ni Ghana, ka ohun to ṣẹlẹ silẹ, wọn ni ayẹwo oku ti wọn ṣe fun Kashy lọjọ kẹwaa, oṣu yii, paapaa fidi ẹ mulẹ pe o ja bọ lati ori ibi to ga ni, o fori gbalẹ, o si dagbere faye.

Apa kan atẹjade naa ṣalayepe lọjọ keje, oṣu kẹta, ọdun 2021, ni Oloogbe ati ọmọ Barrista, pẹlu ọrẹbinrin oloogbe, gba yara mẹta ninu otẹẹli naa lorilẹ-ede Ghana.

Wọn ni loru ọjọ naa ni ọrẹbinrin Kashy ti wọn jọ wa ni yara, sare wa si yara ti Barry Jhay ati olorin Ghana kan wa, o si sọ fun wọn pe ki wọn waa wo Kashy bo ṣe n ṣe bii ẹni ti nnkan kọ lu, o ni iwa odi lo n hu ni yara, o jọ pe nnkan kan ti fẹ si i lara.

Eyi lo mu ọmọ Barrista lọ si yara Kashy, nigba to si debẹ, wọn ni niṣe ni oloogbe yii kọ lu u, to bẹrẹ si i ba a ja. Koda, wọn lo fi kinni kan ṣe e leṣe to jẹ niṣe ni Barry Jhay sare jade ni yara naa pẹlu ẹjẹ lẹnu, apa rẹ ko ka Kashy rara.

Wọn fi kun un pe ẹni to mu yara ti Kashy paapaa jẹrii si i pe oun ri i bo ṣe n fo kiri ile naa, to n pariwo, to si n ṣe bii ẹni ti ẹgun n gun. Ẹni naa da a lẹkun titi, ko dahun, afigba to gbe ara ẹ soke, to si bẹ silẹ lati ori oke alaja mẹrin bi wọn ṣe wi. Wọn ni bo ti ja bọ naa lo pade iku ojiji, nitori ori lo fi gbalẹ bo ṣe balẹ ọhun.

Lẹyin ti Barry Jhay bọ lọwọ ẹ, wọn lo to iṣẹju mẹẹẹdogun to fi lọọ sinmi nibi to jokoo si, asiko naa ni Kashy bẹ silẹ lori oke, wọn ni ọmọ Agbajelọla ko lọwọ kan ninu iku to pa ọmọde olowo to n gbe rẹkọọdu taka-sufee jade naa.

Ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn ((27) ni Kashy to ku yii, ọjọ to pe ọdun mẹtadinlọgbọn naa ni wọn gbe e sin.

Ayẹyẹ ọjọọbi naa ni wọn lo tori ẹ lọ si Ghana to ku si yii, ṣugbọn ko duro ṣe ọjọọbi naa to fi dagbere faye.

 

Leave a Reply