Awọn tọọgi ya wọ aafin Ṣọun Ogbomọṣọ, ori lo ko Kabiesi ati minisita kan yọ

Ọlawale Aajao, Ibadan

Ori lo ko minisita fọrọ ọdọ ati ere idaraya lorileede yii, Ọgbẹni Sunday Dare ati Ṣọun ilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Jimoh Ọladunni Oyewumi (Ajagungbade Kẹta), yọ lọwọ iku tabi ijamba ojiji nigba tawọn ọmọ iṣọta ya lu aafin ọba naa ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ.

Lẹyin ti awọn agbofinro fẹyin pọn Ọba Oyewumi atawọn alejo rẹ gba ẹyinkule jade laafin lawọn janduku naa fi taya dana saafin ọba. Wọn fi apola igi kan ẹsẹ diẹ ninu awọn aga ti awọn alejo Ṣọun fi n jokoo, bẹẹ ni wọn fọ gilaasi oju ferese aafin ọba.

Ere tete lawọn ti ile wọn wa nitosi sa de aafin nigba ti wọn ri eefin ina nla to n ru soke lati ibẹ. Nigba ti wọn debẹ ni wọn ri i pe ina ọhun ko ṣeeṣi ṣẹ yọ nibẹ, awọn ẹruuku lo kina bọle ọba. Ọpọ awọn to n gbọ iroyin iṣẹlẹ yii latokeere si ro pe niṣe laafin ti jona kanlẹ pata.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, lawọn ọdọ ilu Ogbomọṣọ darapọ mọ awọn ẹgbẹ wọn kaakiri orileede yii lati ṣe iwọde alaafia tako bi awọn SARS, iyẹn awọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale nilẹ yii, ṣe n hu awọn iwa ibajẹ bii ipaniyan, ilọnilọwọgba ati oniruuru iwa ọdaran mi-in. Eyi ni wọn si n ṣe lọwọ ti ọkan ninu awọn ọlọpaa to n gbiyanju lati tu awọn olùwọ́de ọhun ka to fi yibọn pa ọmọkunrin kan to n jẹ Jimoh Isiaq.

Iku ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun yii lawọn ọdọ tun ṣe ifẹhonu han le lori lọjọ keji, iyẹn ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti wọn fi kọlu aafin ọba.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, minisita fọrọ ọdọ ati ere idaraya nilẹ yii sọ pe nibi ti awọn alaṣẹ ilu ti n ṣepade lọwọ lori iṣẹlẹ ibanujẹ ọjọ Satide ọhun lawọn tọọgi ti de tijatija.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọmọluabi ni tọmọde tagba ilu Ogbomọṣọ, awọn tọọgi lo darapọ mọ awọn to n ṣe ifẹhonu han yẹn ti wọn fi lo oore-ọfẹ yẹn lati ba nnkan jẹ.

“Nibi ta a ti n ṣepade lọwọ lawọn janduku yẹn waa ka wa mọ. Awọn agbofinro, titi dori awọn ọlọpaa to wọṣọ atawọn ọlọpaa abẹnu ni wọn fi ẹyin pọn emi pẹlu Kabiesi atawọn igbimọ lọbalọba ilu Ogbomọṣọ jade laafin.

Ọgbeni Dare ti oun funra rẹ jẹ ọmọ Ogbomọṣọ waa rọ awọn ọdọ ilu naa lati gba alaafia laaye, ki wọn si yago fun igbesẹ to ba le jẹ ki awọn tọọgi fi orukọ wọn huwa ọdaran.

Nigba to n ṣalaye akitiyan awọn agbofinro lori iṣẹlẹ yii, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi fi awọn ara Ogbomọṣọ lọkan balẹ lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ọlọpaa, pẹlu ikunlọwọ Operation Burst, iyẹn awọn oṣiṣẹ ajọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ niluu Ogbomọṣọ ni wọn ṣi awọn ọmọ iṣọta yẹn lọwọ iwa bàsèjẹ́ yẹn. Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn ọlọpaa ti gbakoso eto aabo ilu Ogbomọsọ, wọn si ti gẹgun yika aafin lati daabo to peye bo ile ọba atawọn araalu.”

Leave a Reply