Awọn ẹruuku tun ya wọ Akinyẹle, n’Ibadan, wọn ṣa iya atọmọ ladaa

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi awọn ẹni ibi kan ṣe n pa awọn eyan nipakupa lagbegbe Akinyẹle, n’Ibadan, awọn ọbayejẹ eeyan naa ti tun ya wọ agbegbe naa, wọn si ṣa iya atọmọ ladaa yannayanna.

Bi awọn ọdaju eeyan yii ṣe ṣa iya ẹi ọdun marundinlaaadọta  naa, Abilekọ Adeọla Bamidele, ladaa niṣaakuṣaa to, kekere tun ni tiẹ lẹgbẹẹ tọmọ ẹ, Dọlapọ Bamidele, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun. Ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, lọmọbinrin naa wa bayii. Tọsantoru lawọn ẹbi atololufẹ ẹ fi gbadura fun un pe ki Ọlọrun fi ibukun si igbiyanju awọn dokita lati gbẹmi ẹ la. Idi ni pe wọn ti ṣa ọmọbinrin naa ju, niṣe ni wọn ṣa a tagbaratagbara bii igba ti awọn alapata ba n ṣa ẹran maaluu ni káárà.

Ni nnkan bii aago kan oru ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, lawọn ẹruuku naa ya wọ agbegbe ti wọn n pe ni Ìsàlẹ̀-Alájá, lAkinyẹle, n’Ibadan, ti wọn si n wọle tọ awọn araadugbo naa lọ lojule-de-ojule.

Ile awọn Bamidele ti wọn fabọ si naa ni wọn ti ṣa iya atọmọ niṣakuṣaa yii, ti wọn si tun ko ẹrọ ibanisọrọ wọn lọ. Oke aja lawọn ẹruuku naa gba wọnu ile wọn.

Abilekọ Bamidele ṣalaye f’AKEDE AGBAYE pe ọmọ oun gan-an ni wọn fẹẹ pa, pe bi oun ṣe fori laku lati gba a silẹ lo jẹ ki wọn ṣa oun naa ladaa, ati pe bi oun ko ba fori laku lati gba a silẹ bẹẹ ni, ọmọ oun naa iba ti wa lara awọn ti iroyin iba tun maa gbe kiri pe wọn tun ti pa lAkinyẹle bayii.

Iya ẹni ọdun marundinlaaadọta yii ṣalaye pe “kọ mi ko si nile, emi ati ọmọ yii (Dọlapọ) la jọ wa nile.  Nigba to di nnkan bii aago kan oru ni mo n gbọ igbe ọmọ mi ninu yara ti to n sun.

“Mo sare dide nilẹ pe ki n lọọ wo ohun to n ṣẹlẹ. Bi mo ṣe de yara ọmọ mi ni mo ri i ti wọn n ṣa a ladaa ni gbogbo ara bii igba ti wọn ba n ṣa maaluu. Bi mo ṣe ṣilẹkun lonitọhun sare pade mi to ṣa emi naa ladaa. Bo ṣe sa lọ niyẹn.

Nibi ti emi atawọn ọmọ mi ti n japoro lọwọ ni wọn ti wọ inu yara ta a ko foonu wa si, ti wọn si ko foonu awa mejeeji lọ.

“Awọn araadugbo wa ni wọn gbe emi atọmọ mi lọ sọsibitu. Wọn si ti lọọ sọ fawọn ọlọpaa nipa ohun to ṣẹlẹ yii.’’

Olugbe adugbo ọhun kan naa ti ko darukọ ẹ fakọroyin wa fidi ẹ mulẹ. O ni, ‘‘Ọdọ tiwa ni wọn kọkọ wa. Wọn fọ bọgilari ati windo ile wa. Awọn meji ni. Wọn mu ada járímọ́dìí lọwọ. Ko si èèkù kankan nidii ẹ, a o mọbi ti wọn ti ri iru ada bẹẹ. Akisa aṣọ ọmọ mi to wa lẹyinkule ni wọn mu ti wọn we mọ ada yẹn. Iyẹn bọ silẹ lọwọ wọn ninu ile wa. A ko waa mọ ibi ti wọn ti ri eyi ti wọn fi ṣe awọn eeyan leṣe yẹn. Nigba ti wọn gburoo ẹsẹ wa ninu ile ni wọn jade.”

 Ko si ẹni to nigboya lati pe ọlọpaa tabi awọn agbofinro ninu awọn eeyan to gbalejo ọran yii, afi lẹyin ti awọn ẹruuku lọ tan. Alaga ẹgbẹ awọn lanlọọdu la gbọ pe wọn sare tẹ̀ laago. Bo si tilẹ jẹ pe lẹsẹkẹsẹ niyẹn ti foonu awọn ọdẹ, awọn ọdẹ ko mọna ibi ti awọn ẹni ibi naa sa gba lọ, nitori bẹẹ ni wọn ko ṣe ri wọn mu.

 Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii lawọn dokita ṣi n ṣiṣẹ takuntakun lati doola ẹmi Dọlapọ ti wọn ṣa ladaa yannayanna. Bẹẹ lawọn ẹbi ẹ n fi adua ti igbiyanju awọn dokita lẹyin pe ki ijanba nla ti wọn fi ṣe ọmọbinrin naa ma ṣe mu ẹmi ẹ lọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to huwa ọdaran yii ni ibamu pẹlu aṣẹ CP Joe Nwachukwu Nwonwu ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ naa.

Leave a Reply