Awọn Fulani yii maa n ṣe bii darandaran lọsan-an, wọn maa n da awọn eeyan lona lalẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Afurasi ọdaran mọkanla lọwọ ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ, Amọtẹkun, fijilante atawọn OPC tẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2021, ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Mẹfa ninu awọn afurasi ọdaran ọhun ni wọn mu fun ẹsun idigunjale lagbegbe Ṣaki, nigba ti ọwọ tẹ awọn marun-un yooku fun ẹsun kan naa lagbegbe Okeho, nijọba ibilẹ Kajọla.

Iran Fulani ni wọn pe awọn mọkọọkanla. Meji ninu wọn paapaa lo si jẹ tẹgbọn-taburo, ọmọ iya ọmọ baba.

Nigba to n ṣalaye bi awọn Amọtẹkun, OPC atawọn fijilante ṣe mu awọn ikọ adigunjale ẹlẹni mẹfa lagbegbe Ṣaki, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ti i ṣe oludari ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ fidi ẹ mulẹ pe “Agbẹ ọlọsin maaluu ni gbogbo aye mọ awọn eeyan naa si, ṣugbọn adigunjale ni wọn, nitori wọn kan fi maaluu ti wọn n da kiri lọsan-an ṣe bojuboju lasan ni, bo ba ti di aajin oru ni wọn yoo dihamọra pẹlu ibọn lati maa ja awọn ero inu ọkọ lole loju popo.

“Maaluu ọhun naa ni wọn n da kiri ti awọn oṣiṣẹ wa (ẹṣọ Amọtẹkun) fi ka wọn mọ ibi ti wọn ti n da awọn arinrinajo lọna loju titi pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro mi-in, ta a si mu wọn pẹlu atilẹyin awọn OPC atawọn fijilante agbegbe yẹn.

“Orukọ awọn mẹfẹẹfa ni Awali Atine, Ibrahim Abu, Shuaib Balau, Ibrahim Musa pẹlu awọn tẹgbọn-taburo kan ti wọn n jẹ Abdullahi Masika ati Umar Aliu Masika

“A ti fa gbogbo wọn le  ọlọpaa lọwọ pẹlu awọn ibọn ti wọn fi n jale, ati owo ta a ka mọ wọn lọwọ pẹlu maaluu mẹtalelọgọsana-an (183) ti wọn fi n ṣe bojuboju ki gbogbo aye le ro pe ọmọluabi eeyan ni wọn”.

O fi kun un pe lanaa yii kan naa lọwọ tẹ awọn maraarun ti wọn mu lagbegbe Okeho, ati pe awọn arufin mọkọọkanla ọhun ti wa lahaamọ awọn agbofinro fun ẹkunrẹrẹ iwadii ati igbesẹ to ba tun kan lẹyin naa.

Leave a Reply