Awo ounjẹ lọmọọdọ yii fọ, lọga ẹ ba fipa rọ ata si i lọfun

Faith Adebọla

Obinrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Ojuigo David ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa tile-ẹjọ ni ki wọn fi i si latari iwa ọdaju ti wọn fẹsun rẹ kan an, wọn ni niṣe lobinrin naa fi tipatipa rọ ata gibigbona gidi si ọmọọdọ ẹ, Ifunnaya, lọfun, diẹ lo ku kọmọ ọdun mẹwaa naa gbabẹ sọda, ẹṣẹ tọmọ naa da ko kọja awo ounjẹ ti wọn lo fọ lọwọ rẹ lọ.

Sibẹ titi dasiko yii lawọn dokita ṣi n sapa lati doola ẹmi ọmọde naa lọsibitu ijọba to wa, latari iṣẹlẹ buruku to waye lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii.

Ba a ṣe gbọ, ọmọọdọ ni Ifunnaya n ṣe lọdọ Abilekọ David yii, wọn ni ko ti i ju oṣu diẹ tọmọde naa de ọdọ rẹ, ile kan naa ni wọn n gbe lọna Aba, lagbegbe Umuahia, ipinlẹ Abia.

Ọkan lara awọn alaamulegbe wọn ti ko fẹ ka durukọ oun sọ fawọn oniroyin pe ọga Ifunnaya yii ti roro ju, o ni ojoojumọ lo n ba ọmọọdọ rẹ yii ja bii orogun, gbogbo igba lo si maa n ka ẹsun si i lẹsẹ pe o ṣẹ oun.

“Tẹ ẹ ba wo ara ọmọ naa, ẹ maa ri oriṣiiriṣii apa lara ẹ, ẹgba lo fi ṣe batani si i lara, ko si si nnkan ti ko le fi na ọmọ ọhun tinu ba n bi i, ohunkohun tọwọ ẹ ba ti ba ni. Igba kan wa to da omi gigbona lu ọmọ naa, to jẹ Ọlọrun lo yọ ọ.

“Ṣugbọn eyi tobinrin naa ṣe lọjọ Sannde yii lo ga ju, a o mọ boya o fẹẹ diidi pa ọmọọdọ ẹ yii ni. Niṣe lo da ata si omi gbigbona, o si ki ọmọ naa mọlẹ, o fipa rọ ata gbigbona naa si lọfun.

Gbogbo ete ati ẹnu ọmọ yii lo bo yanmọyanmọ, ọmọ naa ko si le sọrọ daadaa mọ, pẹlu inira lo fi n lọgun ṣugbọn ko ṣee ṣe fun un. O ṣeeyan laaanu gidi.

Boya nigba toun naa ri ọṣẹ buruku to ṣe fọmọọdọ rẹ yii lo fi sare mu un gba ọna kọrọ kan, o mu un lọ sileetaja oogun (kẹmiisi) to wa laduugbo wọn, ṣugbọn ẹni to wa ni ṣọọbu naa loun ko le ba a tọju ọmọbinrin yii, o ni ọsibitu ni ko mu un lọ. Obinrin buruku yii loun ko le mu un lọ sọsibitu, eyi lo mu ki onikẹmiisi naa pe awọn aladuugbo le obinrin naa lori, ọrọ dariwo nigba tawọn abiyamọ fẹẹ maa lu ọdaju ọga to fẹẹ pa ọmọọdọ ẹ yii, lawọn kan lara wọn ba pe ileeṣẹ ọlọpaa lori aago.”

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn gbe ọmọọdọ ọhun, Ifunnaya, lọ sọsibitu, ibẹ lo ṣi wa ti wọn ti n tọju ẹ lọwọ.
Bakan naa ni wọn fi pampẹ ofin gbe Ojuigo David, wọn lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n bojuto iwa ọdaran abẹle fẹẹ gba a lalejo, ibẹ loun naa wa bayii to n gbatẹgun lọdọ wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Abia, Geoffrey Ogbonna fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti taari afurasi ọdaran ọhun sile-ẹjọ, kootu si ti paṣẹ pe ko ṣi wa lakata awọn ọlọpaa na.

Leave a Reply