Adugbo kan ti wọn pe ni AYA Roundabout, nibi ti awọn to fẹẹ wọde yii ti ni in lọkan lati pe jọ si laaarọ yii lawọn ṣọja ti duro sibẹ wamu, ti wọn si n dari bi mọto ṣe n lọ, to n bọ lagbegbe naa. Wọn ko si fun awọn oluwọde yii lanfaani lati pe jọ sibẹ. Ki awọn ọdọ to n ṣewọde yii too de lawọn ṣọja yii ti gbakoso ibe.
Wọn ni lati le fopin si wahala to n ṣẹlẹ niluu Abuja lori iwọde ta ko awọn SARS, ni wọn ṣe ko wọn jade lati daabo bo araalu.
ALAROYE gbọ pe ọna mi-in patapata gbaa ni iwọde tawọn eeyan n ṣe l’Abuja ọhun gba yọ, nibi ti awọn janduku kan ti n kọlu awọn to n wọde ta ko SARS atawọn to n ṣe iwọde lati fara mọ wọn.
Ohun ta a gbọ ni pe ọkan lara awọn eeyan ti wọn gun lọbe lasiko ikọlu ọhun lẹmi ẹ ti bọ bayii ni ọsibitu ti wọn sare gbe e lọ.
Kaakiri awọn adugbo niluu Abuja lawọn ṣọja wa bayii lati koju awọn janduku to n fi iwọde ọhun da ilu ru.
Bi eleyii ṣe n lọ lawọn to n wọde yii tun ti kora wọn jọ si agbegbe Airport, atawọn adugbo mi-in mi-in l’Abuja, ti wọn si n ba eto wọn lọ.
Édaku é bami wipe se iye owo osun ti awon egbe won ngba kakiri agbaye ni awon na ngba sugbon ao le da awon omoleyin lebi tori asé awon oga ni won ntéle