Ṣọja, ọlọpaa ati ọtẹlẹmuyẹ kọju ija si Sunday Igboho lọna Ibadan, wọn fẹẹ mu un tipatipa

Awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ agbofinro bii ogoji la gbọ pe wọn dena de ọkan ninu awọn ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ni ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Loju ọna marosẹ Ibadan si Eko la gbọ pe awọn ọlọpaa, awọn ṣọja atawọn ọtẹlẹmuyẹ bii ogun ti dena de e, ti wọn si fẹẹ mu un.

Gẹgẹ bi minisita fun ileeṣẹ ofurufu nilẹ wa tẹlẹ, Oloye Femi Fani-Kayọde ti fi lede, o ṣalaye pe ‘‘Mo ṣẹṣẹ ba arakunrin mi, Sunday Igboho, sọrọ tan laipẹ yii ni, o si sọ fun mi pe pẹlu ijakadi ni awọn ṣọja, ọlọpaa, awọn ọtẹlẹmuyẹ fi fẹẹ mu oun loju ọna marosẹ Ibadan si Eko lasiko ti oun n lọ siluu Eko lati lọọ ri Baba Ayọ Adebanjọ.’’

Fani-Kayọde bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, o ni iwa buruku ti o si lewu ni awọn eeyan naa hu.

O fi kun un pe ti awọn ẹṣọ alaabo ba fẹẹ ri ọkunrin yii, ohun kan ti wọn ni lati ṣe ni ki wọn ranṣẹ si i pe ko wa si ọọfiisi wọn.

Fani Kayọde ni, ‘‘Mi o mọ ẹṣẹ kan kan ti wọn ni ọkunrin yii ṣẹ. Bakan naa ni mo n ranṣẹ ikilọ si ijọba apapọ pe akin ọkunrin niIgboho si ogunlọgọ ọmọ Yoruba, bi wọn ba si fi mu un ti wọn ti i mọle, yoo jẹ aṣiṣẹ nla fun wọn.’’

Leave a Reply