Awọn ṣọja ri meje gba pada ninu awọn ọmọọlewe Kebbi ti wọn ji gbe, ọkan ti ku ninu wọn

Faith Adebọla

Rẹrẹ run lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba tawọn ṣọja ilẹ wa lọọ dana ibọn ya awọn janduku agbebọn ti wọn lọọ ji awọn akẹkọọ-binrin ọmọleewe FGC ko nipinlẹ Kebbi, wọn ri akẹkọọ marun-un ati olukọ meji gba pada, akẹkọọ kan ku, wọn si pa ọpọ awọn agbebọn ọhun nipakupa.

Afẹmọju Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn agbebọn kan ya bo ọgba ileewe kọlẹẹji tijọba apapọ, Federal Government Girls College, to wa niluu Birnin Yauri, nijọba ibilẹ Yauri, nipinlẹ Kebbi, ni nnkan bii aago meji kọja iṣẹju diẹ lọganjọ oru.

Kidaa awọn akẹkọọ-binrin ni wọn n kawe nileewe naa, inu ọgba ileewe ọhun si ni wọn n gbe pẹlu awọn olukọ wọn ti wọn n gbe ile ijọba.

Ọlọpaa kan to gbiyanju lati ṣediwọ fawọn afẹmiṣofo naa ni wọn pa nifọnna ifọnṣu, ti wọn si fipa mu ọkan lara awọn sikiọriti to n ṣọ ileewe ọhun pe ko ṣamọna awọn lọ sibi tawọn ọmọleewe naa n sun si ti wọn fi ji wọn ko.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn lawọn ọmọleewe ti wọn ji ko naa ko din laaadọrin (70), pẹlu marun-un lara awọn olukọ wọn ti wọn n gbe’nu ọgba ileewe naa.

Amọ ṣa, ninu atẹjade kan lati ọfiisi Alukoro awọn ologun, Ọgagun Onyema Nwachukwu fidi ẹ mulẹ pe awọn ọmoogun ilẹ wa ti lọọ koju awọn janduku naa, wọn si ri meje gba pada ninu awọn ti wọn ji gbe ọhun.

O ni bọrọ ọhun ṣe to ileeṣẹ ologun leti lawọn ti tọpasẹ awọn kọlọransi ẹda yii lọ, awọn si lepa wọn lati ilu Yauri gba agbegbe Riyao de Sombo, nipinlẹ Kebbi.

O lawọn janduku naa ti pin ar awọn si ẹgbẹ meji, awọn kan ko awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn ji ko pamọ, nigba ti ẹgbẹ keji wa pẹlu awọn maaluu ti wọn ji ko pẹlu.

O lawọn ọmoogun oju ofurufu naa n tọpasẹ awọn olubi wọnyi lati oke, wọn si n pese isọfunni nipa bi wọn ṣe rin fawọn to n jagun lori ilẹ, eyi lo mu kawọn ri awọn meje yii gba pada.

Wọn tun ri awọn maaluu to ju ọgọrun-un mẹjọ (800) lọ gba pada lọwọ wọn ninu mọto ti wọn ko wọn si, wọn si ti wa awọn maaluu ọhun pada saarin ilu Kebbi, nile ijọba.

Ọgagun Nwachukwu sọ pawọn jagunjagun ṣi n ba akitiyan wọn lọ, awọn o si ni i duro titi tawọn maa fi rẹyin awọn ajinigbe naa tawọn si maa ri awọn akẹkọọ ati olukọ to ṣẹku gba pada lalaafia.

O kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi akẹkọọ-binrin kan to doloogbe, wọn ni sagbasula naa lo pin ọmọbinrin ọhun lẹmi-in, nigba tagbara rẹ ko gbe e mọ.

Atẹjade naa fi kun un pe, akiyesi tawọn ṣe ni pe adajọ ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Kebbi lo ni ọkọ ti wọn fi ji awọn ọmọleewe naa gbe wọgbo, iwadii si ti bẹrẹ lori bọrọ naa ṣe jẹ gan-an.

Leave a Reply