Faith Adebọla, Eko
Nnkan o ti i rọgbọ lorileede Olominira Guinea lasiko yii, paapaa ni ilu Conakry, ti i ṣe olu-ilu orileede naa, pẹlu ba a ṣe gbọ pe awọn ṣọja tinu n bi kan ti mu Aarẹ orileede naa, Alpha Conde, ẹni ọdun mẹtalelọgọrin (83), wọn ti fi i sahaamọ, awọn ọmoogun rẹpẹtẹ si ti wa nile agbara wọn.
Ninu fotọ kan ti wọn ju sori atẹ ayelujara, ileeṣẹ oniroyin agbaye nni, Reuters, ṣafihan Aarẹ Conde, to jokoo yakata sori aga kan, o fọwọ lẹran, o n wo orere aye, awọn ọmoogun ọlọtẹ si yi i ka tibọntibọn, wọn ni ibẹ ni wọn ṣi mu un pamọ si.
Lati afẹmọju ọjọ Aiku, Sannde yii, ni iro ibọn ti n dun lakọlakọ ni olu-ilu naa, tawọn ṣọja si ya bo ọfiisi Aarẹ ati gbogbo ọna to kọja niluu ọhun.
Wọn ni pẹlu ibẹrubojo lawọn eeyan to fẹẹ jade fi sa pada sile wọn, ti kaluku si tilẹkun mọri, bẹẹ ni iro ibọn ko dawọ duro, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to le sọ pato ohun to ṣẹlẹ, tori awọn ṣọja naa ko ti i ṣe ikede kan lori redio tabi tẹlifiṣan lati jẹ kawọn eeyan mọ bo ṣe n lọ.
Reuter ni awọn ọmoogun ọlọtẹ to fẹẹ gbajọba ni wọn wa nidii iṣẹlẹ naa, o si jọ pe wọn ti fẹẹ rọwọ mu, Ọgagun ọmọ-bibi ilẹ Faranse kan, Mamady Doumbouya, ni wọn lo ṣaaju awọn ọmoogun ọhun.
Reuter ni ọkan lara awọn ṣọja naa ti sọ pe awọn ti tilẹkun irinajo ọkọ ofurufu ati tori omi, gbogbo ẹnubode to wọ orileede naa lawọn si ti tipa bayii na.
Fidio kan ti wọn tun ju sori ẹrọ ayelujara ṣafihan Aarẹ ti wọn mu naa, tẹnikan n bi i leere boya wọn ṣe e leṣe tabi bẹẹ kọ, ṣugbọn Conde ko fesi kan, niṣe lo kan n wo bii gbure ọlọbọrọ.
Inu oṣu kẹta, ọdun to kọja yii, ni Baba arugbo naa bẹrẹ si i lo saa kẹta ijọba rẹ, lẹyin to ti dọgbọn pa kadara iwe ofin orileede naa da, lati le faaye gba lilo saa mẹta nipo Aarẹ, yatọ si meji to ti wa lakọọlẹ orileede ọhun fun igba pipẹ.
Latigba ti wọn si ti kede rẹ poun lo wọle ibo fun saa kẹta ni ẹkọ ko ti ṣoju mimu ni Guinea, ara o rọ okun ara o rọ adiẹ ni.