Aderouonmu Kazeem
Ki alaafia le jọba nijọba ibilẹ Ifakọ-Ijaye ati Ojokoro, awọn ẹya Yoruba, ati Hausa, to n gbe nibẹ ti ṣeleri ibagbepọ alaafia.
Nibi ipade kan ti ileeṣẹ Oloogun (ṣoja) pe awọn aṣoju ẹya mejeeji yii sí ni wọn ti seleri ọhun lati gbagbe rogbodiyan to bẹ silẹ lọsẹ to kọja laarin awọn Hausa ati Yoruba ti wọn n gbe ladugbo kan to n jẹ Fagba, ni ilu Eko.
Ọgagun Mohammed Estu-Ndagi to ṣeto ipade ọhun, ninu eyi ti Kọnẹẹli Ibrahim Umar ti ṣoju fun un, sọ pe ipade alaafia naa ṣe pàtàkì, ati pe lara ojúṣe ijọba ni lati ṣeto alaafia saarin araalu tirufẹ wahala tawọn eeyan ọhun ba ara wọn fa ba waye.
Awọn Ṣoja to da sọrọ ọhun ti waa rọ awọn araalu ki wọn fi ifẹ ati irẹpọ gidi ba ara wọn gbe, ati pe ẹnikẹni to ba da wahala silẹ, ijọba ko ni i foju rere wo iru ẹni bẹẹ, bẹẹ ni yoo da ara ẹ lẹbi paapaa.
Ohun tawọn agbaagba kan lagbegbe naa sọ ni pe wahala to bẹ silẹ ọhun ko ṣai ni i ṣe pẹlu rogbodiyan to sẹlẹ lasiko iwọde tako awọn ọlọpaa SARS, ati pe aini-sùúrù awọn ọdọ agbegbe naa pẹlu ohun to da ìjà ìgboro náà silẹ.
Ibrahim Umar ti waa rọ awọn eeyan lati gba alaafia laaye, bẹẹ lọ ba awọn eeyan ti wọn padanu awọn eeyan ati dukia wọn kẹdun gidigidi.