Awọn aṣaaju Fulani to n gbe lẹyin awọn ọmọ wọn to n huwa ọdaran lo n da wahala silẹ- Seriki Ṣáṣá

Ọlawale Ajao, Ibadan

Sarikin Fulani Ṣáṣá, n’Ibadan, Alhaji Haruna Mai Yasin, ti sọ pe awọn aṣaaju Fúlàní ló n pọn awọn ero ẹyin wọn tó n huwa ọdaran. Eyi ló si n kan ìyẹ́ mọ awọn eeyan naa lapa lati tubọ máa huwa ọdaran láwùjọ.

Yasin sọrọ yii nibi ipade pajawiri ti awọn alákòóso eto aabo ipinlẹ Ọyọ ṣe lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, lọjọ Ẹtì, Furaidee, to kọja.

Nitori oriṣiiriṣii ipenija to n ba eto aabo lẹnu ọjọ mẹta yii lo mu ki CP Vivian Ngozi Ọnadẹkọ ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ pe awọn aṣáájú àwùjọ lati jiroro lori ọna abayọ si ìṣòro náà.

 

Níbẹ lọba awọn Fúlàní Ṣáṣá ti la ọrọ mọlẹ pe kò sí Seriki tabi adari awọn Fúlàní ilu tabi agbegbe kan tí yóò sọ pe oun ko da awọn tọọgi to n da ilu ru lagbegbe oun mọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Eeyan ko le jẹ Seriki nibi kan ko sọ pe oun ko mọ awọn ọdaran abẹ oun. Fúlàní to ba sọ bẹẹ, irọ lo n pa.

“Bi Seriki kan bá sọ pe òun ko mo awọn ọdaran abẹ oun, bawo lo ṣe wa n lọọ gba wọn silẹ latimọle. Gbígbè ti awọn adari wọn n gbè lẹyin wọn ni ko jẹ ki awọn ọdaran aarin wọn ti pa iwá ọdaran ọwọ wọn ti.

“Awọn Fúlàní n ji Fúlàní ẹgbẹ wọn pàápàá gbe to jẹ pe awọn adari wọn ló máa san owo ti wọn fi máa gba wọn silẹ.

“Ọna ti emi ro pe a le gba bọ lọwọ ìṣòro tó n dojú kọ wa lori eto aabo ni lati máa tu aṣiri awọn ọdaran àdúgbò wa fawọn ọlọpaa. Kíkọ tà a kọ láti máa ṣe bẹẹ la ṣe n gbe ninu ifoya bayii.

 

Adari ẹgbẹ to n ri sí ọrọ idagbasoke ilu Igangan, Ọgbẹni Ọladokun Ọladiran gba pe ko bojumu fàwọn Fulani lati máa yan Seriki (ọba) niluu oniluu.

“Awa náà ṣáà gbé ẹyin odi ri, bakan naa la ni awọn to ṣi n gbé ẹyin odi di ba a ṣe n wi yìí. Èèyàn lè ní ẹgbẹ loriṣiiriṣii, ṣugbọn ki i ṣe bíi ka sọ pe a fẹẹ jọba tabi baálẹ̀.

“Ọba ki í pé meji laafin. Ìyẹn lajèjì ko ṣe lẹtọọ lati jẹ baálẹ̀ niluu oniluu, nitori ẹni tó bá máa jẹ baálẹ̀ gbọdọ ni ilẹ to n ṣakoso le lori.

Nitori idi eyi, ti Abdul Kadiri ba máa padà sí Igangan, o ni lati fọwọ siwee lori awọn ofin atawọn ilana tó gbọdọ tẹle ko tóo lè padà síbẹ”.

Ọga agba awọn olopaa ipinlẹ Ọyọ waa rọ gbogbo ara ipinlẹ naa lati gba alaafia laaye, ki wọn si máa fi àwọn arufin adugbo kaluku wọn sun awọn agbofinro.

Awọn lọgaalọgaa lẹnu iṣẹ agbofinro loriṣiiriṣii bii ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ (DSS), awọn aṣọbode, sifu difẹnsi, ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn kopa nibi ipade ọhun, titi dori CP Fatai Owoṣeni ti i ṣe oludamọran fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lori eto aabo.

Leave a Reply