Awọn aṣaaju PDP ẹkun Ọyọ fa Makinde kalẹ lati dupo gomina fun saa keji

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party PDP, ẹkun idibo apapọ Ọyọ, nipinlẹ Ọyọ ti fọwọ sí ki gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣẹyi Makinde dije dupò ninu idibo ọdún 2023 lati lo saa keji nipo gomina.

Awọn adari ẹgbẹ PDP agbegbe Ọyọ, eyi to duro fun ẹkun idibo ijọba apaapọ Ọyọ nipinlẹ naa ni wọn sọrọ yii nibi ipade ti wọn ṣe nílùú Ọyọ Alaafin ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Bakan naa ni wọn panu pọ fọwọ si Olóyè Bisi Ilaka gẹgẹ bii adari ẹgbẹ oṣelu PDP lẹkun idibo naa, ti wọn sì fi Ọnarebu James Olukunle ti i ṣe igbakeji alaga ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ọyọ ṣe alaga ẹgbẹ oṣelu ọhun lẹkun idibo naa.

Ẹkun idibo Ọjọ lo ko awọn ijọba ibilẹ bíi Afijio, Atiba, Ila-Oorun Ọyọ àti ìjọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ọyọ sinu.

Awijare wọn ni pe, lẹnu ọdún kan aabọ ti Makinde lo nipo gomina, o ti ṣe bẹbẹ, o sí yẹ ki wọn fún ùn lore-ọfẹ lati tun ṣejọba náà lẹẹkan sí i.

Lara àṣeyọrí Makinde ti wọn tọka si gẹgẹ bii ohun amuyẹ to jẹ ko kunju oṣunwọn lati dije dupò gomina lẹẹkeji lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni àtúnkọ́ ọja Akẹ̀sán, niluu Ọyọ, atunṣe papa iṣere Durbar, l’Ọyọọ, atunṣe awọn oju ọna kan kaakiri ilu Ọyọ ati bó ṣe sọ Fasiti LAUTECH to wa niluu Ogbomọṣọ di dukia ipinlẹ Ọyọ nikan lati iye ọdun yii ti ileewe naa ti jẹ àjùmọ̀ni laarin ipinlẹ Ọyọ ati ipinlẹ Ọṣun.

Awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP ẹkun idibo Ọyọ yii waa gba awọn to dipo oṣelu mu lagbegbe naa niyanju lati maa yọju sí àwọn eeyan agbegbe wọn lóòrèkóòrè, ki wọn le maa ṣe koriya fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lati le duro ṣinṣin ninu ẹgbẹ naa.

Leave a Reply