Awọn Aṣofin agba ti fọwọ si i ki Mahmud Yakub maa ṣe alaga INEC lọ

Ile-igbimọ aṣofin agba ti fọwọ si i bayii pe ki Ọjọgbọn Mahmud Yakub to jẹ alaga ajọ eleto idibo ilẹ wa telẹ maa tẹ siwaju gẹgẹ bii alaga ajọ naa.

Loni-in, Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, ni wọn fọwọ si i, lẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọwe ranṣẹ si wọn pe oun tun ti yan ọkunrin ọhun ni alaga fun ajọ INEC.

Sááju asiko yii ni Mahmood Yakub ti kọkọ lo ọdun mẹrin gẹgẹ bii alaga fun ajọ ọhun, bẹẹ lawọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba ti sọ pe oloootọ eeyan ni, to ṣiṣẹ ẹ daradara.

Sẹnetọ Kabiru Gaya sọ niwaju awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin agba pe ọkunrin naa ṣiṣẹ ẹ daadaa, bẹẹ ni inu awọn dun si i lori bo ṣe dahun awọn ibeere tawọn bi i pẹlu itẹriba.

 

Leave a Reply