Awọn aṣofin buwọ lu aba eto iṣuna ọdun 2021 l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin oṣu kan ti Gomina Gboyega Oyetọla ti gbe aba eto iṣuna tipinlẹ Ọṣun yoo lo lọdun to n bọ lọ sile-igbimọ aṣofin, awọn aṣofin ti buwọ lu u lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Aba eto iṣuna naa ni apapọ owo inu rẹ din diẹ ni biliọnu lọna aadọfa naira (#109,855,051,640). Owo tijọba yoo na lori awọn iṣẹ akanṣe le diẹ ni biliọnu lọna aadọta naira, nigba ti owo ti yoo ba awọn ti ki i ṣe iṣẹ akanṣe lọ din diẹ ni biliọnu lọna aadọta naira.

Abẹnugan ile, Rt. Hon. Timothy Owoẹyẹ, gboriyin fun awọn ẹgbẹ rẹ fun ifaraji ati ifọwọsowọpọ wọn lati ṣiṣẹ lori aba eto iṣuna naa kiakia. O ni nnkan ti bọjẹẹti naa da le lori ju lọ ni bi ipinlẹ Ọṣun yoo ṣe jajabọ lori wahala ti ajakalẹ arun korona ti mu ba eto iṣuna ninu ọdun yii.

Bakan naa lo ni ọrọ awọn ọdọ ko ipa pataki ninu eto iṣuna naa nitori bii biliọnu kan aabọ naira (#1.4b) nijọba ya sọtọ lati na lori idagbasoke awọn ọdọ lọdun to n bọ.

Owoẹyẹ ke si awọn ileeṣẹ ijọba lati tẹpa mọṣẹ, ki wọn si ṣe gbogbo nnkan ti wọn kọ silẹ ninu aba eto iṣuna naa pe awọn fẹẹ ṣe. O ni loorekoore lawọn yoo maa ṣepade pẹlu awọn ileeṣẹ naa lati mọ bi wọn ṣe n gbiyanju si lẹnu iṣẹ wọn.

Lori irọkẹkẹ wahala korona to tun wa nilẹ bayii, Owoẹyẹ rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati ma ṣe tura silẹ rara, o ni gbogbo alakalẹ ati ilana ti yoo dena itankalẹ arun naa di dandan fun gbogbo eeyan lati maa tẹle bayii.

O ni kiakia lawọn yoo gbe aba ti awọn buwọ lu naa lọ sọdọ gomina, ki oun naa le buwọ lu u, ko si le di ofin to ṣe e mu lo.

 

Leave a Reply