Awọn aṣofin ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP marun-un ti darapọ mọ ẹgbẹ mi-in

Monisọla Saka
Awọn sẹnetọ marun-un lati inu ẹgbẹ oṣelu APC ati ẹyọ kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti kọwe fipo silẹ ninu ẹgbẹ wọn.
Awọn aṣofin ọhun ni Ahmad Babba Kaita lati apa Ariwa Katsina (Katsina North), Lawal Yahaya Gumau lati apa Guusu Bauchi (Bauchi South), Francis Alimikhena ti apa Ariwa ipinlẹ Edo (Edo North) ati Haliru Jika Dauda to n ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun Bauchi ( Bauchi Central), nigba ti Francis Ezenwa Onyewuchi to jẹ ọmọ ẹgbẹ Alaburada (PDP), wa lati Ila-Oorun Imo (Imo East).
Nigba ti Babba Kaita ati Alimikhena lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ alatako, iyẹn PDP, Gumau ati Jika ni tiwọn ya lọ si NNPP, nigba ti Onyewuchi ti inu ẹgbẹ PDP bọ si ẹgbẹ Labour Party.
Iroyin ifipo-silẹ ati didarapọ ẹgbẹ oṣelu wọn lo wa ninu lẹta mẹrin ọtọọtọ ti olori igbimọ aṣofin agba, Ahmad Lawan, ka lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, si eti gbogbo awọn aṣofin to wa nijooko nile.
Ninu lẹta Babba Kaita lo ti ni, “Gẹgẹ bii sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Ariwa nipinlẹ Katsina, mo n fi akoko yii fi to yin leti pe mo fẹẹ fipo mi silẹ kuro ninu ẹgbẹ APC, bẹẹ ni mo n fi to yin leti pe mo ti di ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
“Kikuro ninu ẹgbẹ APC mi ko ṣẹyin ojuṣaaju ti awọn ijọba ipinlẹ Katsina atawọn adari ẹgbẹ nipinlẹ ọhun ṣe fawọn eekan ẹgbẹ naa, nibi ti awọn keekeeke bii temi yii ko ti lẹnu nibẹ.
“Wọn si ti fi idunnu ati ayọ gba mi sinu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Katsina”.
Sẹnetọ Alimikhena ni tiẹ ṣalaye pe idi ti oun fi fẹgbẹ APC silẹ ko ju wahala ati rogbodiyan to maa n fojoojumọ ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa lọ, paapaa ju lọ ni ẹkun ibi ti oun n ṣoju, eyi ti ko bikita fawọn alaṣẹ, ti ko si si ibawi tabi afojusun nibẹ.
Ohun ti pupọ awọn aṣofin yii ri di mu fun kikuro ninu ẹgbẹ ti wọn wa tẹlẹ ko ju aisododo ati magomago to kun inu ẹgbẹ ti wọn fi silẹ lọ.
Kikuro awọn aṣofin mẹtẹẹta yii ti din iye awọn sẹnetọ lẹgbẹ APC ku si mẹrindinlaaadọrin(66) lati aadọrin (70) nileegbimọ aṣofin agba, gẹgẹ bi atẹjade ti Oluranlọwọ pataki si olori ileegbimọ aṣofin agba lori eto iroyin, Dokita Ezrel Tabiowo gbe jade.

Leave a Reply