Awọn aṣofin gbe igbimọ dide lati fopin si wahala awọn ajagungbalẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ile-igbimọ aṣofin Eko ti fi aidunnu wọn han si bi wahala awọn janduku ti wọn n pera wọn ni ‘ọmọ onilẹ’ tabi ‘ajagungbalẹ’ ṣe tun di lemọlemọ nipinlẹ Eko, wọn lawọn gbọdọ wa ojuutu si wahala ọhun, wọn si ti gbe igbimọ kan dide lori ẹ.

Nibi apero wọn to waye ni Alausa, Ikẹja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni aṣofin to n ṣoju agbegbe Ẹpẹ kin-in-ni, Ọnarebu Abiọdun Tọbun, ti ṣalaye pe ojoojumọ ni lẹta ẹsun tawọn eeyan ti wọn ko sọwọ awọn janduku wọnyi kọ n rọjọ sile aṣofin naa.

O ni iṣẹlẹ naa buru debii pe awọn agbofinro kan tun dara pọ mọ awọn janduku yii lati gba ile ati ilẹ lọwọ ẹni to ni in pẹlu ibọn ati ada ati oogun abẹnu gọngọ.

O fẹrẹ jẹ gbogbo awọn aṣofin to sọrọ lori iṣẹlẹ yii lo fi erongba kan naa han, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu bi ẹka ileeṣẹ gomina to yẹ ko ṣiṣẹ lori ofin ti wọn ṣe lati mojuto ọrọ yii ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu iṣẹ naa.

Ọnarebu Akeem Ṣokunle (Oṣodi-Isọlọ Kin-in-ni), David Sẹntoji (Badagry Keji) ati Adedamọla Kasunmu (Ikẹja Kin-in-ni) ati Rotimi Olowo (Ṣomolu Kin-in-ni) dabaa pe ki ẹka eto idajọ gbe akanṣẹ ẹka ti yoo maa gbọ ẹsun to jẹ mọ ọrọ ilẹ l’Ekoo kalẹ, ki wọn pe olori ajọ amuṣẹṣe ti gomina yan lori ọrọ ilẹ waa wi tẹnu ẹ, ki wọn si sọ fun gomina lati wa nnkan ṣe si ọrọ naa. Abẹnugan Mudashiru Ọbasa sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ foun lati ri iya tawọn janduku fi n jẹ awọn araalu lori ọrọ yii.

Lẹyin apero yii, wọn pinnu lati gbe igbimọ ẹlẹni meje kan kalẹ, eyi ti Igbakeji Abẹnugan, Ọnarebu Ṣaina Agunbiade (Ikorodu Kin-in-ni) jẹ alaga fun, lati ṣeto apero kan laarin ọsẹ mẹta, eyi ti awọn araalu atawọn tọrọ kan yoo ti le mu imọran wa, loju ọna ati wa ojuutu to maa gbeṣẹ ju lọ sọrọ yii.

Leave a Reply