Awọn aṣofin Eko koro oju si fiimu tawọn oṣere n gbe jade, wọn ni palapala ti pọ ju ninu ẹ

Faith Adebọla, Eko

Ileegbimọ aṣofin Eko ti paṣẹ fun igbimọ alabẹṣekele ile lori irinajo igbafẹ ati aṣa, lati bẹrẹ si i ṣagbeyẹwo ofin ipinlẹ Eko lori agbejade fiimu, sinima ati ayẹwo ere ori itage, lati le mu adinku ba awọn fiimu ti ko bode mu, ateyi to n tabuku si aṣa ati iwa ọmọluabi lawujọ. Wọn lawọn fiimu tawọn oṣere n gbe jade lasiko yii wa lara ohun to n ṣakoba fawọn ọdọ atawọn ọmọde.

Nibi ijiroro to waye lori ẹsun ti Olori ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ, Ọnarebu S. O. B. Agunbiade, mu wa lasiko ijokoo wọn to waye ni l’Alausa, n’Ikẹja, ni wọn ti sọrọ ọhun.

Ọnarebu Agunbiade ni iwọkuwọ, isọkusọ ati iṣekuṣe ti wọpọ ninu awọn fiimu agbelewo tawọn oṣere tiata n gbe jade lasiko yii, o si ti nipa buruku lori awọn ọdọ lawujọ. O dabaa pe ki wọn wọgi le ofin to ṣakoso gbigbe fiimu jade, ki wọn si ṣofin mi-in to maa ni ifiyajẹni to gbopọn fun awọn oṣere to ba huwa ta ko ofin naa.

Bakan naa l’Ọnarebu Joseph Kẹhinde sọ pe iyatọ gbọọrọ-gbọọrọ lo wa laarin awọn oṣere tiata aye ọjọun ati awọn tode oni, o ni iwa ati iṣe ọpọ ninu awọn awọn onitiata ode oni ki i ṣe awokọṣe rere fawọn ọdọ, tori awọn kan ninu wọn n bora, wọn n wọ aṣọkaṣọ, wọn n ṣira silẹ, wọn si n yinbọn bii pe wọn n kọ awọn to n wo fiimu lẹkọọ ibọn yinyin.

Ọnarebu Bisi Yusuf ati Ọnarebu Ṣolaja naa sọrọ nipa awọn aleebu to wa ninu awọn fiimu ti wọn n gbe jade lasiko yii, wọn bẹnu atẹ lu ere ori tẹlifiṣan BBNaija, wọn si kọminu si aipeye to maa n wa ninu bi wọn ṣe n tumọ ede Yoruba si ede oyinbo (sub-title) ninu fiimu wọn.

Awọn aṣofin naa tun  bẹnu atẹ lu bawọn obi ki i ṣe bikita fawọn ọmọ wọn mọ, ati bawọn olukọ kan ṣe maa n gbọjẹgẹ lori ibawi ati ẹkọ iwa rere nileewe.

Nipari, awọn aṣofin naa fẹnuko, nipasẹ Igbakeji Abẹnugan wọn, Ọnarebu AbdulWasi Ẹṣinlokun, to dari ijiroro ọjọ naa, pe ki igbimọ tọrọ kan lọọ ṣayẹwo ofin to ṣakoso gbigbe fiimu jade nipinlẹ Eko, ki wọn si kan si kọmiṣanna tọrọ kan ati ajọ to n bojuto iṣẹ sinima nipinlẹ naa, lati wa ojuutu si ọrọ yii, ki wọn si jabọ pada fun ile.

Leave a Reply