Awọn aṣofin Eko ni kijọba sanwo fawọn teeyan wọn ku ninu ajalu ile to wo n’Ikoyi

Faith Adebọla, Eko

Ileegbimọ aṣofin Eko ti sọ pe ki Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ṣeto lati sanwo to jọju fawọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn sinu ajalu ile alaja mọkanlelogun to wo lọjọ ki-in-ni, oṣu kọkanla yii, gẹgẹ bii ọkan lara igbesẹ lati tu wọn ninu.

Awọn aṣofin naa tun ke si gomina ipinlẹ Eko lati paṣẹ fawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si eto ile kikọ atawọn ileeṣẹ tọrọ ile kikọ kan nipinlẹ Eko lati san ṣokoto wọn, ki kaluku wọn si bẹrẹ si i ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ lakọtun lati ri i pe awọn to n kọle ni gbogbo origun mẹrẹẹrin ipinlẹ naa tẹle ofin ati alakalẹ to yẹ ki wọn tẹle, tabi ki wọn gbe igbesẹ ofin lori wọn.

Nibi apero wọn to waye lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ni gbọngan apero awọn aṣofin naa to wa l’Alausa, Ikẹja, ni wọn ti sọrọ yii.

Ọkọọkan awọn aṣofin ipinlẹ Eko to sọrọ, titi kan Olori wọn, Ọnarebu Mudaṣiru Ọbasa, ni wọn fi ẹdun ọkan ati aidunnu han si ijamba to ṣẹlẹ lọjọ Aje to lọ lọhun-un, nigba ti ile awoṣifila alaja mọkanlelogun ti wọn n kọ lọwọ lọna Gerrard, n’Ikoyi, l’Erekuṣu Eko, ṣadeede ya lulẹ, to si fẹmi ọpọ eeyan ṣofo, yatọ si awọn to fara pa ati ọpọ dukia to ṣegbe.

Ba a ṣe gbọ, iye oku eeyan ti wọn ri gbe jade ninu awoku naa ti di mẹrinlelogoji, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii, ti ọpọ lara wọn ṣi n gba itọju iwosan lọwọ lawọn oṣibitu ijọba, bẹẹ lawọn mọlẹbi bii ogoji ṣi n pariwo pe awọn o ti i foju kan awọn eeyan awọn, ti wọn gbagbọ pe wọn ṣi ha saarin alapa awoku naa, bo tilẹ jẹ pe iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lati doola ẹmi wọn, tabi ko oku wọn jade.

Ọnarebu Ọbasa sọ pe iṣẹlẹ aburu gbaa ni bi ẹmi ati dukia to ṣeyebiye ṣe ṣegbe yii.

“A gbọdọ mu suuru ki awọn igbimọ oluṣewadii pari iwadii wọn ka too mọ nnkan ta a maa sọ. Ṣugbọn o daju pe awọn ajọ ta a ni ki wọn ṣiṣẹ lori abojuto ile kikọ nipinlẹ Eko ko ṣiṣẹ wọn doju ami rara. Gẹgẹ bii aṣofin, a gbọdọ ṣabojuto ọrọ yii bo ṣe yẹ. A ni lati maa ṣayẹwo awọn ti wọn fẹẹ da okoowo ile kikọ silẹ l’Ekoo, a si gbọdọ kaaanu awọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn sinu ijamba yii. Ijọba gbọdọ tu awọn mọlẹbi wọnyi loju gidi, tori tawọn ajọ ati ileeṣẹ ijọba tọrọ kan ba ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ ni, iṣẹlẹ aburu yii ko ni i waye rara.”

Ọnarebu Nurein Akinsanya to n ṣoju agbegbe Mushin ki-in-ni lọ kọkọ dabaa pe ki ile jiroro lori iṣẹlẹ to waye ọhun, ti wọn si gba aba rẹ wọle. Akinsanya ni bi ile ṣe n ṣadeede ya lulẹ kaakiri ipinlẹ Eko lẹnu ọjọ mẹta yii n kọ oun lominu gidi. O ni iyalẹnu lo jẹ lati maa gbọ pe ile alaja mẹẹẹdogun ti ajọ LASPPPA faṣẹ si di alaja mọkandinlogun ti ẹnikan o si sọrọ titi ti ile naa fi waa di pakute iku yii. O tun mẹnuba ile alaja marun-un to wo ni Lẹkki lọjọsi, ati alaja mẹta to ya lulẹ ni adugbo Ita-Faaji n’Isalẹ Eko.

Agbẹnusọ awọn aṣofin naa, Ọnarebu David Sẹtọnji lati agbegbe Badagry sọ pe ọpọ nnkan lo maa fa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ yii, titi kan bi wọn ṣe yaworan ile naa, nnkan eelo ti wọn fi kọ ọ, ati agbekalẹ rẹ.

Lẹyin eyi lawọn aṣofin naa, ati gbogbo awọn to wa ninu gbọngan ọhun dide duro fun iṣẹju kan lati bọla fawọn to padanu ẹmi wọn, wọn si ṣadura fun wọn.

Leave a Reply