Awọn aṣofin Eko ti fofin de fifi maaluu jẹko ni gbangba, wọn tun ṣofin lori VAT

Faith Adebọla, Eko

Bi’ṣẹ o ba pẹ’ni, ẹnikan ki i pẹ iṣẹ, lawọn aṣofin Eko fi abadofin lori sisọ fifi maaluu jẹko ni gbangba deewọ nipinlẹ Eko ṣe, ati ofin to maa fun ijọba ipinlẹ Eko laṣẹ ati agbara lati maa gba owo ori ọja ti wọn n pe ni VAT (Value Added Tax) nipinlẹ Eko, pẹlu bawọn aṣofin naa ṣe fontẹ lu awọn abadofin mejeeji lai sọsẹ.

Ibuwọlu wọn ọhun waye ninu ipade ti wọn ṣe nile aṣofin ọhun lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee yii, nibẹ ni wọn ti ṣagbeyẹwo awọn abadofin mejeeji, ti wọn si fontẹ lu u.

Ṣe ṣaaju ni wọn ti kọkọ jiroro lori awọn abadofin ọhun lẹẹmeji, lẹyin eyi, wọn pe apero itagbangba l’Ọjọruu, Wẹsidee, lati mọ ero araalu atawọn ti ọrọ ofin mejeeji naa kan gbọngbọn, ọgọọrọ awọn to pesẹ sibi apero naa ni wọn fara mọ awọn abadofin ọhun.

Amọ ṣa, diẹ lara awọn to sọrọ lasiko apero mu awọn aba to yatọ wa, eyi ti awọn aṣofin naa lawọn yoo gbe yẹwo, awọn yoo si ṣiṣẹ lori wọn.

Lẹyin ijiroro wọn nile aṣofin Eko, Ọnarebu Mudasiru Ọbasa to jẹ Abẹnugan awọn ile aṣofin naa beere pe ki awọn to ba fọwọ si fifofin de fifi ẹran jẹko ni gbangba nipinlẹ Eko sọ pe “Bẹẹ ni,” kawọn ti ko ba si fara mọ ọn sọ pe “Bẹẹ kọ”, pẹlu ariwo nla lawọn aṣofin naa fi dahun ‘Bẹẹni’ si awọn abadofin ọhun, ko sẹni to sọ “Bẹẹ kọ” rara.

Bẹẹ ni Ọbasa gba awọn abadofin naa wọle, o si paṣẹ fun akọwe ile aṣofin naa lati pese ẹda to peye nigin-nigin, ko si taari rẹ sọfiisi Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu, ko le buwọ lu u, kawọn ofin naa le bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ-o-sọka nipinlẹ Eko.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ alaye nipa awọn abadofin mejeeji yii wa fun yin laipẹ.

Leave a Reply