Awọn aṣofin Eko yọ alaga kansu mẹta nipo, wọn larufin ni wọn

Faith Adebọla, Eko

Ile-igbimọ aṣofin Eko ti fọwọ osi juwe ile fawọn alaga ijọba ibilẹ mẹta nipinlẹ Eko, Ọnarebu Ogidan Mukandasi Ọlaitan, ni kansu Lẹkki, Ọnarebu Suleiman Jẹlili, nijọba ibilẹ Alimọṣhọ, ati Ọnarebu Tajudeen Ajide ti ijọba ibilẹ Surulere, wọn ni wọn n tapa sofin to yẹ ki wọn tẹle.

Nibi ijokoo awọn aṣofin ọhun to waye l’Alausa, Ikẹja, lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, niṣẹlẹ ọhun ti waye.

Aṣofin ‘Bisi Yusuf to n ṣoju agbegbe Alimọṣọ lo kọkọ dabaa pe ki wọn juwe ọna ile fun alaga kansu Lẹkki, o ni ọkunrin naa ko fẹẹ tẹle awọn ilana ati ofin to n ṣakoso ijọba ibilẹ, o ni aye fa-mi-lete-n-tutọ lo n jẹ, ko si bọwọ fawọn aṣofin ipinlẹ rara.

O ni gbogbo anfaani to yẹ ki alaga ọhun fun awọn kansẹlọ rẹ lati ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ lo gbegi le, diẹ lo si ku ki rogbodiyan bẹ silẹ lagbegbe ijọba ibilẹ ọhun ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin latari iwa ta-lo-maa-mu-mi to ni alaga kansu naa n hu.

Bo ṣe n pari ọrọ rẹ ni Ọnarebu Fatai Mọjeed to n soju Ibẹju-Lẹkki ki-in-ni dide, o ni iwa tawọn alaga ijọba ibilẹ Surulere ati Alimọṣhọ tun buru ju ti Lẹkki lọ.

O ni ki i ṣe pe Ọgbẹni Jẹlili ati Ajide n tapa sofin nikan ni, o ni gbogbo amọran ati aba tawọn fun wọn lati mu nnkan rọrun, ki wọn si gbaju mọ iṣẹ imayegbadun faraalu ni wọn kọti ọgbọnyin si, ati pe apẹẹrẹ buruku ni wọn jẹ fawọn alaga ijọba ibilẹ yooku.

Olori ile naa, Mudaṣiru Ọbasa, sọ pe awọn o le laju silẹ ki awọn alaga ijọba ibilẹ sọ ara wọn di aṣẹ-ma-lu, ẹran ọba, nipinlẹ Eko. O ni pẹlu bi eto idibo ṣe n sun mọle, tawọn alaga tuntun mi-in maa bọ sipo, bawọn ko ba gbe igbeṣẹ to yẹ, ko ni i dara kawọn alaga to n bọ ba apẹẹrẹ iwakiwa ati titẹ ofin loju  tawọn alaga mẹtẹẹta yii gun le.

Nigba to beere pe kawọn ti wọn fara mọ mọ iyọnipo awọn alaga naa sọ pe “Bẹẹ ni,” gbogbo ile lo pariwo “bẹẹ ni,” ni Ọbasa ba lu iyọnipo naa lontẹ, o si paṣẹ fun akọwe ile lati tete jẹ ki lẹta iyọnipo wọn kan wọn lara lẹyẹ-o-sọka.

Leave a Reply