Awọn aṣofin faṣẹ si lilo ẹrọ ayelujara fun eto idibo gbogbogbo

Faith Adebọla

Awọn aṣofin ti yi ero wọn pada lori ilo ẹrọ ayelujara lasiko idibo apapọ, wọn ti fọwọ si i pe ki ajọ eleto idibo INEC pinnu bo ba ṣe wu wọn lati lo ẹrọ ti wọn fi n dibo, tabi fi esi ibo sọwọ lori ẹrọ ayelujara taarata lati ibudo idibo.

Lasiko ijiroro lori abadofin kan ti wọn fẹẹ fi ṣatunṣe si ofin eto idibo gbogbogboo, eyi to waye ninu gbọgan ipade awọn aṣofin agba l’Abuja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ipinnu naa ti waye.

Ọkan ninu awọn aba to da awuyewuye silẹ naa ni eyi to wa ni ipo kẹtadinlọgọta, to da lori bawọn eeyan yoo ṣe dibo ati bi wọn yoo ṣe fi esi ibo ranṣẹ.

Latigba tawọn aṣofin naa ti beere pe kawọn eeyan sọ ero ati aba wọn lori abadofin yii ni ọpọ ti dabaa pe lilo ẹrọ lati fi dibo ati fifi esi idibo ṣọwọ taarata lori ẹrọ ayelujura lo bode mu, dipo kiko iwe idibo ati esi idibo kiri.

Ṣugbọn abadofin naa da awuyewuye silẹ nileegbimọ aṣoju-ṣofin ati lọdọ awọn aṣofin agba nigba ti wọn n ṣagbeyẹwo awọn aba naa loṣu keje to kọja yii. Ọpọ awọn aṣofin lo ta ko lilo intanẹẹti lati fi esi ibo ranṣẹ, wọn ni intanẹẹti ko si lawọn ibudo idibo kan, ati lawọn ijọba ibilẹ mi-in, ati pe lilo intanẹẹti le mu ariyanjiyan dani.

Nigba tawọn aṣoju-ṣofin ti buwọ lu lilo imọ ẹrọ, awọn aṣofin agba ko fọwọ si i, eyi lo mu ki wọn gbe igbimọ mi-in dide lati tun ṣayẹwo si aidọgba to wa ninu ofin eto idibo naa.

Abọ igbimọ yii lawọn aṣofin agba jiroro le lori lọjọIṣẹgun, wọn si fẹnuko lati yi ila kẹtadinlọgọta naa pada, si: “Ajọ (INEC) le pinnu lati fi esi idibo ṣọwọ nipa ilo ẹrọ ayelujara ni gbogbo ibi ti wọn ba ti ri i pe o ba a mu lati ṣe bẹ, awọn ni yoo si pinnu ilana to dara ju lati lo, titi kan lilo ẹrọ kọmputa ati awọn ẹrọ igbalode fun eto idibo.”

Awọn abadofin mi-in ti wọn ti ṣatunṣe si ni:
Nọmba kẹtalelogoji, eyi to ka pe: “Ajọ (INEC) yoo pese apoti idibo, ẹrọ igbalode ti wọn fi n dibo tabi awọn ẹrọ mi-in ti wọn lero pe yoo wulo fun eto idibo to muna doko.”

Ajọ (INEC) ni yoo pinnu awọn fọọmu to yẹ lati kọ ọrọ kun lasiko idibo, ati fun eto idibo bi wọn ba ṣe ro o si.

Awọn aṣoju ẹgbẹ gbọdọ lanfaani lati ri bi wọn ṣe n ko awọn nnkan eelo idibo lati ọfiisi INEC lọ si awọn ibudo idibo kaakiri.”

Wọn tun ṣatunṣe si ila kẹtalelọgọta: “Oludari eto idibo gbọdọ fi esi idibo ṣọwọ, titi kan aropọ iye awọn ondibo ti wọn faṣẹ si lati dibo, ati aropọ iwe idibo gẹgẹ bi ajọ INEC ba ṣe la a kalẹ.”

Nigba ti olori awọn aṣofin naa beere pe kawọn to fara mọ awọn aba yii sọ pe “bẹẹ ni”, ariwo awọn to sọ pe awọn fara mọ ọn pọ ju ti awọn to sọ pe awọn ko fara mọ ọn lọ, ni wọn ba lu u lontẹ.

Leave a Reply