Awọn aṣofin fontẹ lu awọn ọgagun ti  Aarẹ Tinubu fọrukọ wọn ranṣẹ

Ni bayii, awọn aṣofin agba, niluu Abuja, ti fontẹ lu gbogbo awọn ọgagun ti olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, forukọ wọn ranṣẹ pe ki wọn yẹ wọn wo daadaa, ki wọn si fontẹ lu wọn ki wọn le maa ba iṣẹ ilu lọ gẹgẹ bii erongba rẹ.

Aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni apapọ awọn ọmọ ileegbimọ ọhun jokoo, ni nnkan bii aago mọkanla aarọ, ti wọn si beere ọrọ lẹnu gbogbo wọn pata gẹgẹ bi wọn ti ṣe maa n ṣe fawọn ti wọn ba forukọ wọn ranṣẹ.

Ayẹwo sawọn ọgagun ọhun to waye ninu gbọngan awọn aṣofin naa ni Olori wọn, Senetọ Godswill Akpabio, ti wa lori ijokoo ni gbogbo akoko ti wọn n ye awọn ọgagun naa wo finni-finni.

Lara awọn ẹni ti wọn beere ọrọ lọwọ wọn ni: Ọgagun Christopher Musa, ẹni to maa dipo eto aabo orileede yii mu (Chief Of Defence Staff), Ọgagun Taoreed Lagbaja, ẹni to maa dipo olori awọn ọmọ ogun soja mu, (Chief Of Army Staff), Ọgagun Emmanuel Ogalla, ẹni to maa dipo awọn ọmọ ogun oju omi mu (Chief Of Naval Staff), ati Ọgagun Hassan Abubarkar, ẹni to maa dipo awọn ogun oju ofurufu mu (Chief Of Air Staff).

Ọkọọkan ni wọn beere ọrọ lọwọ wọn titi ti wọn fi pari ayẹwo ọhun.

Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ni Aarẹ Tinubu mu orukọ awọn ọgagun naa lọ siwaju awọn aṣofin pe ki wọn fontẹ lu wọn, ki wọn le tete maa ba iṣẹ ilu toun gbe fun wọn lọ. Idahun si ibeere Tinubu lawọn aṣofin naa ti mu ṣẹ bayii.

Leave a Reply