Awọn aṣofin ni kawọn alaga ijọba ibilẹ mẹtala lọọ rọọkun nile l’Ọyọọ

Ọrẹoluwa Adedeji

Ni Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, ni ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ jawe gbele-ẹ fun alaga ijọba ibilẹ mẹtala, wọn ni ki wọn lọọ rọọkun nile titi ọjọ mi-in, ọjọọre.

Eyi waye nitori bi wọn ṣe ni awọn alaga naa kuna lati ṣalaye awọn ohun eelo ti wọn fi n ṣiṣẹ oko to wa ni akata wọn nigba ti awọn aṣofin beere fun un.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni awọn aṣofin yii ti kọkọ ranṣẹ sawọn alaga kansu naa pe ki wọn waa ṣalaye nipa awọn ohun eelo iṣẹ oko bii katakata, awọn ohun eelo ti wọn fi n pa’ko ati bẹẹ bẹẹ lọ tijọba ko fun wọn, ṣugbọn ti awọn eeyan naa ko dahun.

Nitori bi pupọ ninu awọn eeyan naa ko ṣe ja ọrọ yii kunra lo mu ki wọn tun fi iwe mi-in ranṣẹ si wọn lọjọ kẹtalelogun, oṣu yii, pe ki wọn waa ṣalaye awọn nnkan oko to wa lọwọ wọn naa, ati pe ẹnikẹni to ba kọ lati ṣe bẹẹ ninu wọn, awọn yoo jawee gbele-ẹ fun un ni.

Pẹlu bi wọn ṣe kọ lati mu aṣẹ awọn aṣofin yii ṣẹ lo mu ki wọn fofin de mẹtala ninu wọn.  Awọn alaga fidi-hẹ mẹfa ati ti Onidagbasoke  marun-un lọrọ naa kan.

Awọn alaga ijọba ibilẹ fidi-hẹ tọrọ kan ni Ila-Oorun Akinyẹle, Ido, Oluyọle, Ila-Oorun Ọyọ, Aarin-Gbungbun Ogbomọṣọ ati Ariwa-Iwọ-Oorun Ibadan.

Leave a Reply