Awọn aṣofin ni ki Lai Muhammed waa ṣalaye ofin tijọba fi de Tuita fawọn kia

Awọn aṣoju-ṣofin apapọ niluu Abuja ti paṣẹ pe ki Minisita feto iroyin ilẹ wa, Alaaji Lai Mohammed, yọju sawọn ni kiamọsa lati waa ṣalaye ibi tijọba apapọ ti ri ofin ti wọn fi de ikanni agbọrọkaye Tuita nilẹẹwa, fawọn.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lọrọ naa waye nibi ijokoo apero wọn nileegbimọ wọn lolu-ilu ilẹ wa, Abuja.

Olori awọn aṣofin ọhun, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, lo gbe igbimọ kan kalẹ ni pajawiri, o ni ki wọn ṣewadii, ki wọn si jabọ pada fun ile laarin ọjọ mẹwaa, bi iṣu ṣe ku, ti ọbẹ si bẹ ẹ lori ọrọ Tuita yii atijọba apapọ ilẹ wa.

Fẹmi ni ki wọn ke si Alaaji Lai Mohammed lati yọju sawọn aṣofin naa ni waranṣeṣa, ko si ṣalaye ohun to fa a, ohun tijọba ni lọkan ti wọn fi fofin de Tuita lasiko yii, ati bi ifofinde naa yoo ṣe pẹ to.

O tun ni ki Alaaji Lai waa ṣalaye iru ofin ti wọn fi de Tuita yii, ibi ti ofin naa ti wa, ati boya o ba iwe ofin ilẹ wa mu.

Fẹmi ni apa kan ojuṣe awọn aṣofin lo jẹ lati yiri awọn ipinnu ati aṣẹ tijọba apapọ n pa wo boya o wa ni ibamu pẹlu iwe ofin ilẹ wa, ati lati ri i pe ijọba ko fiya jẹ araalu lai nidii tabi ki wọn fi ẹtọ wọn du wọn.

O ni latigba tijọba ti kede ifofin de Tuita yii lọrọ naa ti da awuyewuye gidi silẹ laarin ilu, titi dasiko yii si lawọn eeyan jannkan jannkan n sọ ero wọn lori ifofin de naa.

“Ta a ba wo bi ọrọ yii ṣe da ariyanjiyan silẹ laarin awọn ọmọ orileede yii atawọn eeyan ilẹ okeere paapaa, ko si idi ti a fi gbọdọ fakoko ṣofo lori rẹ rara, mo si rọ igbimọ yii lati ṣiṣẹ iwadii wọn lai fakoko falẹ rara.

O ni ileegbimọ aṣoju-ṣofin n wo Tuita atawọn ikanni agbọrọkaye mi-in, gbogbo wọn lo ṣe pataki, ti wọn si n ko ipa ribiribi ninu eto ibara-ẹni-sọrọ ati ti okoowo, awọn o si le laju silẹ lai wadii nipa ohunkohun to ba n kọ araalu lominu.

O ni kawọn igbimọ toun yan naa tun ke si ẹnikẹni ti wọn ba ro pe o ni ohun kan tabi meji lati sọ lori ọrọ yii, ki wọn si mu abọ iwadii wọn wa laipẹ.

Leave a Reply