Awọn aṣofin Ọṣun fun Oyetọla lanfaani lati yan alamoojuto si gbogbo ijọba ibilẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla

 

Ile-igbimọ aṣofin Ọṣun ti buwọ lu ofin ti yoo mu atunṣe ba bi wọn ṣe n ṣakoso ijọba ibilẹ.

Abẹnugan ile, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, lo ṣagbatẹru ofin naa, ninu eyi to ti ni kawọn aṣofin foju wo ofin ọhun, to ti wa nilẹ latọdun 2016, ki wọn si mu atunṣe to tọ ba a.

Ni bayii ti wọn ti buwọ lu atunṣe ofin naa, Gomina Gboyega Oyetọla ti lanfaani lati yan awọn eeyan si iṣakoso awọn ijọba ibilẹ to ṣofo bayii.

Ninu ofin naa, niwọn igba ti wọn ba ti tu awọn alakoso ijọba ibilẹ ka, ti idibo ko si ti i waye, gomina yoo yan igbimọ fidi-ẹ (caretaker) lati wa nibẹ fodidi oṣu mẹfa.

Lara awọn ti gomina yoo yan ni alaga, igbakeji alaga, akọwe ati aṣoju kan lati wọọdu kọọkan to wa nijọba ibilẹ naa, awọn ọmọ ile si gbọdọ fọwọ si orukọ ti gomina ba gbe wa ki wọn too kede wọn.

A oo ranti pe ọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun yii, ni ọdun mẹta awọn alakooso ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun pe, ti gomina si paṣẹ pe ki wọn gbe iṣakoso le oṣiṣẹ ijọba to wa nipele to ga ju lọwọ.

 

Leave a Reply