Awọn aṣofin Ogun ni ki EFCC waa tọpinpin Odusolu, ọga OPIC tẹlẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ileegbimọ aṣofin Ogun kede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹsan-an yii, pe owo to sọnu lasiko iṣakoso Amofin Babajide Odusolu, alakooso OPIC tẹlẹ, iyẹn Ogun State Property and Investemnt Corporation, le ni biliọnu meji aabọ naira, wọn si paṣẹ fun ọkunrin naa lati da ogoji miliọnu ti ko ri alaye ṣe lori ẹ lọdun 2019 pada sapo ijọba ipinlẹ Ogun. Oṣu mẹfa ni wọn fun un lati fi da owo yii pada.

Nigba ti awọn aṣofin naa jokoo lọfiisi wọn l’Oke-Mosan lọjọ naa ni wọn sọ pe ki awọn ajọ to n tọpinpin iwa ibajẹ bii EFCC, tudii Odusolu wo, nitori ọpọ owo ipinlẹ Ogun to ha si i lọwọ yii nilo alaye gidi.

Ọnarebu Musẹfiu Lamidi to lewaju igbimọ to ṣewadii owo naa lo gbe e kalẹ niwaju gbogbo ile, o si ṣalaye bi abajade iwadii wọn laarin ọdun 2015 si 2019 ṣe lọ.

Wọn ni akọsile banki ni 2019, ṣafihan ẹẹdẹgbẹrin o le mẹrindinlọgbọn (726m), biliọnu meji aabọ lo si din, eyi to yẹ ko wọle sileeṣẹ ijọba naa.

Ilẹ kan ti wọn ta n’Iṣẹri, to jẹ ẹẹkta mẹjọ ati meji (8.2 hectares), ti wọn ta lowo perete (164m), ile igbimọ ni kawọn to ra a lọọ mọ pe irọ ni wọn ra. Wọn ni lasiko ti saa Babajide fẹẹ tan lo ta ilẹ naa fun Rainerhill Internationals Services, owo to si ta a yii kere buruku si iye ti ilẹ naa to gan-an.

Wọn tun fi kun un pe miliọnu ẹgbẹta le mẹjọ (608m) ti wọn fofin de lawọn banki mẹrindinlogun ko gbọdọ ri bẹẹ. Awọn aṣofin sọ pe ki òté ti wọn gbe le owo naa kuro kia, nitori owo to le wulo fawọn iṣẹ idagbasoke ni.

Otẹẹli nla alarabara (5 star hotel) ti wọn ni wọn fẹẹ kọ s’Ikẹja lasiko Odusolu, eyi ti wọn fi miliọnu marundinlaaadọta (45m) gba iwe rẹ, ṣugbọn ti ko sẹni to ri otẹẹli oun soju ri, wọn ni iwadii gbọdọ waye lori ohun naa, ara iṣẹ tawọn ajọ to n wadii iwa ọdaran gbọdọ ṣe ni.

Owo kan naa tun wa to jẹ ẹẹdẹgbẹrun miliọnu naira (881.5m), ko tun si alaye gidi kan nidii iyẹn naa, owo ṣaa wọgbo naa ni. Eyi naa gbọdọ pada sọwọ ijọba Ogun bawọn aṣofin ṣe wi.

Odusolu ko yọju sileegbimọ lọjọ yii, ṣugbọn gbogbo iṣẹ ti wọn ran si i lo ti bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ o sọka.

Leave a Reply