Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ohun ti ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun n ba Goriọla Hassan fa nipa ọba ilu Imobi ti ọkunrin naa n pe ara ẹ ti gba ibomi-in yọ bayii, awọn aṣofin ti bẹ awọn agbofinro ipinlẹ naa lọwẹ lati mu un nibikibi ti wọn ba ti ri i ki ọjọ mẹrinla too pe.
Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla, tawọn aṣofin yii tun jokoo ipade lọfiisi wọn, l’Oke-Mosan, ni wọn tun ṣiwee iranti kan Goriọla, ti wọn si fohun ṣọkan pe laarin ọjọ mẹrinla tawọn fi ọrọ yii sita, kawọn agbofinro mu Goriọla, ki wọn si fa a le awọn lọwọ.
Eyi ko ṣẹyin bo ṣe jẹ pe awọn aṣofin yii ti paṣẹ pe ki ọkunrin to ni oun ni ọba Imobi Ijẹbu, nijọba ibilẹ Ila- Oorun Ijẹbu, naa yee pe ara ẹ lọba, ṣugbọn ti ko da wọn lohun, ti wọn tun ranṣẹ pe e lẹẹmẹta, ti ko tun yọju si wọn.
Ẹsun mi-in tawọn aṣofin tori ẹ ni kawọn agbofinro mu Goriọla, ọkọ Ayọ Adesanya tẹlẹ, ni pe niṣe lo tun mu ile kan to jẹ ti ijọba, to sọ ọ di tiẹ, to n lo o fun lilo tara ẹ, to si n tapa sofin ijọba.
Wọn ni iwa to le da omi alaafia ilu ru ni Goriọla n hu bo ṣe n jaye ọba nipo ti ko tọ si i.
Wọn fi kun un pe bawọn agbofinro ko ba tete kapa ọkunrin naa nipa fifi ọwọ ofin mu un, iwa to n hu yoo da wahala silẹ n’Imobi.
Bakan naa lawọn aṣofin sọ pe kijọba kede Goriọla Hassan gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa, pẹlu bo ṣe mu ile kan tijọba kọ si Fọtẹdo, Imobi, lati maa fi ta oogun fawọn eeyan, to sọ ọ di tiẹ, to si n lo o.
Wọn ni kawọn araalu tijọba ṣe ibẹ fun gba a lọwọ ẹ.
Igbimọ to n ri si ọrọ oye jije nileegbimọ aṣofin Ogun, eyi ti Ọnarebu Bọlanle Ajayi jẹ alaga ẹ lo jokoo lori ọrọ yii, Ọnarebu Ganiyu Oyedeji naa fọwọ si i, bẹẹ ni gbogbo aṣofin ile naa fohun kan dahun pe awọn fọwọ si ohun ti ile n fẹ lori Goriọla. Olori ile igbimọ, Taiwo Ọlakunle Oluọmọ wa nijokoo pẹlu.
Ẹ o ranti pe ọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun 2021 ni ile igbimọ yii kọkọ ranṣẹ si Goriọla Hassan pe ko wa, ti ko yọju. Wọn tun pe e lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ kan naa, ko tun lọ, ki wọn too tun ni ko wa lọjọ keji, oṣu kẹwaa, ṣugbọn ti ọkunrin naa ko yọju si wọn.
Eyi lo fa a ti wọn fi waa paṣẹ pe kawọn agbofinro mu un, ki wọn si fa a le ileegbimọ to n wa a naa lọwọ, ko le waa ṣalaye ara ẹ lori ipo ọba ilu Imobi to wa.
ALAROYE pe Goriọla Hassan lori aago lati gbọ alaye rẹ lori ọrọ yii, ṣugbọn ko gbe ipe naa.