Awọn aṣofin Ọyọ fẹẹ sọ Oloogbe Ayinde Barrister di manigbagbe ninu itan

Eto ti bẹrẹ bayii lati ṣe ohun ti yoo sọ orukọ Oloogbe Sikiru Ayinde Barrister di manigbagbe ninu itan. Ileegbimọ aṣofin Ọyọ ti gbe aba kan dide lati sọ olorin ọmọ Ibadan naa di ohun tawọn eeyan yoo maa ranti laelae.

Wọn tiẹ ti taari aba naa si ẹka to n maa n sọ aba di ofin nile yii, ki wọn ṣiṣẹ tiwọn le e lori lo ku.

Ọdun kọkanla ree tawọn kan ti wa nidii ki wọn sọ Barry Wonder di manigbagbe, boya nipa fifi orukọ rẹ sọ ibi kan, tabi gbigbẹ ere rẹ sibi to jẹ ọgbagade, ti wọn yoo si maa fi i pe ibẹ. O si le jẹ ẹka ileewe tabi ileeṣẹ kan ni wọn yoo fi sọri Sikiru Ayinde Barista ọmọ Agbajelọla.

Ọpọ eeyan lo gboriyin fun aba tawọn aṣofin naa da yii, paapaa awọn ọmọ Ibadan. Wọn ni akọrin to fi iṣẹ rẹ tun aye ọpọ eeyan ṣe ni Barrister, ko si jọọyan loju pe ijọba fun un loye MFR ko too jade laye, nitori o ṣiṣẹ fun ipo naa ni.

Lati waa jẹ ki iṣẹ to ṣe silẹ maa fọhun lẹyin rẹ, ki orukọ agba ọjẹ onifuji naa ma si ṣe di ohun igbagbe, wọn ni o daa bawọn aṣofin Ọyọ ṣe fẹẹ sọ ọ di manigbagbe yẹn.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2010, ni Barrister jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta (62)

Leave a Reply