Awọn aṣofin wa naa o wulo, tara wọn nikan ni wọn n ṣe

Aṣọfin kan, Sẹnetọ Ndume, lo sọrọ kan, ọrọ naa yoo si da bii isọkusọ loju awọn aṣofin ẹlẹgbẹ rẹ to ku ni. Nigba ti ọrọ idaji owo-oṣu ti ijọba Buhari san fawọn olukọ yunifasiti yii bẹrẹ, aṣofin naa ni eyi ko dara, bo ba jẹ ijọba ko kuku lowo lọwọ ni wọn ṣe fẹẹ da kinni naa sagidi, ki wọn ge owo-oṣu tawọn aṣofin naa funra wọn sidaji, ki wọn maa san idaji owo-oṣu fawọn, ki wọn si maa san odidi owo fawọn olukọ yunifasiti yii. Ohun ti aṣofin yii n sọ ni pe ko si iṣẹ gidi kan ti awọn n ṣe to fi yẹ ki awọn maa gba iye owo-oṣu ti awọn n gba, ati pe bi ipenija iru eyi to n ṣẹlẹ yii ba waye, awọn ti awọn jẹ aṣofin lo yẹ ki awọn kọkọ fi ara di i, ki i ṣe araalu lo yẹ ko maa jiya ti wọn o mọdi rara. Ọkunrin to ronu bayii, ki i ṣe pe ọpọlọ tirẹ daru o, bẹẹ ni ki i ṣe pe ko mọ ohun to n sọ, ọrọ gidi lo n sọ, nitori orilẹ-ede ti awọn oloṣelu ba ti n gbowo ju awọn oṣiṣẹ gidi lọ, iru orile-ede bẹẹ ki i nilaari. Awọn oloṣelu tiwa ki i ro eleyii, ọna ti wọn yoo fi gbowo ju awọn to n foju mejeeji ṣiṣẹ lawọn n wa, bi ọrọ ba si ti di ariyanjiyan bayii, ẹyin ijọba ni wọn yoo wa, nibi ti awọn ti n jẹ niyẹn. Ohun to fa iru ọrọ ti olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin sare sọ niyẹn, to sọ pe ki i ṣe dandan ki ijọba sanwo oṣu fawọn olukọ yunifasiti to yanṣẹ lodi. A wa ṣe pe awọn eeyan yii yanṣẹ lodi nitori ọlẹ tiwọn ni, abi nitori ifẹ tiwọn nikan, ṣebi lẹyin ti wọn ti ba ijọba sọrọ titi ti ijọba ko gbọ ni. Ọpọ ohun ti wọn n beere fun, ṣebi pe ki ẹkọ yunifasiti ilẹ wa le dara ni. Ṣugbọn Gbajabiamila ni ko yẹ ki wọn gba owo oṣu wọn lodidi, awọn yoo ṣẹṣẹ bẹ Buhari ko ṣaanu wọn ni, bii pe onibaara ni wọn, awọn atọrọjẹ lasan! Ohun to si ya ni lẹnu ni bi ọrọ naa ti ṣe sare kan  Gbajabiamila bẹẹ, to si waa jẹ ibi to dara ju lati tete da si ọrọ ni ibi ti wọn ko ti ni i sanwo fawọn olukọ wọnyi. Oun kọ ni minista fun eto ẹkọ o, bẹẹ ni ki i ṣe oun ni Buhari tabi igbakeji rẹ, koda iṣẹ tirẹ ki i ṣe akoso eto ijọba, ofin ni wọn ni ko maa ṣe, ofin ti yoo mu ohun gbogbo lọ deede fun wa. Ṣugbọn Gbaja pa iṣẹ ofin ti, eyi to mu un lara ni bi awọn olukọ ko ṣe ni i gbowo oṣu. Oun si wa nibẹ to n gba owo ẹ deede o, to n lo ohun gbogbo lọfẹẹ lọfẹẹ, to n nawo ijọba bo ti ṣe fẹ, to si le jẹ oke-okun lawọn ọmọ rẹ wa ti wọn ti n kawe tiwọn. O pẹ ti a ti n sọ ọ pe nigba ti orile-ede kan ba n dara, ẹ wo awọn aṣofin ibẹ wo daadaa, wọn yoo jẹ awọn aṣofin to ṣee mu yangan nibi gbogbo, awọn aṣofin to jẹ ọrọ araalu ni yoo ṣaaju ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe. Ileegbimọ aṣofin to ba jẹ ijọba lo n gbeja, to ba jẹ ọrẹ awọn to n ṣejọba ni wọn fẹẹ maa ṣe, iru ile igbimọ aṣofin bẹẹ yoo kuna, wọn ko ni i wulo faraalu, nitori wọn ti fihan pe ki i ṣe taraalu lawọn ba lọ sibẹ, tawọn oloṣelu ẹlẹgbẹ wọn ni. Ohun to n ṣẹlẹ si awọn aṣofin wa ni Naijiria yii niyẹn. Asiko ti a wa yii, ti nnkan gbogbo doju de fun Naijiria yii, asiko ti ko yẹ ka mọriri, ka si ri iṣẹ awọn aṣofin wa ree, nitori ofin ti wọn ba ṣe ni olori ilu gbọdọ tẹle, olori ilu ti ko ba si tẹle aṣẹ tabi ofin ti awọn ileegbimọ ba ṣe, yiyọ ni wọn n yọ olori ijọba bẹẹ danu. Ṣugbọn awọn aṣofin tiwa ko laya, wọn ko to ẹni ti i ṣe ofin ti wọn yoo ni dandan Buhari gbọdọ tẹle e. Bi o ba ṣe iru ofin bẹẹ, ti awọn eeyan ijọba naa ba ti fi EFCC halẹ mọ wọn, tabi ti wọn fi ọga ọlọpaa halẹ mọ wọn, kaluku wọn yoo sa pada, wọn yoo kori bọle, nitori ọwọ awọn naa ki i mọ, wọn yoo ti ṣe kinni kan ti awọn yẹn fi le pariwo wọn sita, tabi ki wọn fi ofin tiwọn gbe wọn. Ẹni to ba ti huwa ọdaran ri, tabi to n huwa ọdaran lọwọlọwọ, iru wọn ko lẹtọọ lati wa nileegbimọ, nitori wọn ko niwulo nibẹ, ibẹru ko ni i jẹ ki wọn le ṣe nnkan gidi kan. Bi Naijiria yoo ba dara, awọn aṣofin wa ni iṣẹ gidi lati ṣe, wọn gbọdọ ji giri, ki wọn fi ọrọ owo, ọrọ kọntiraati, ọrọ ipo oṣelu silẹ, ki wọn siṣẹ fun araalu, ki araalu le maa royin wọn si daadaa. Eyi ti wọn n ṣe wọnyi, ti wọn n gbeja ijọba Buhari to n fiya jẹ araalu yii, eleyii ko ni i fun wọn lorukọ to niyi laarin ilu, koda ko ni i sọ wọn di ẹni apọnle nibi kan, ẹni abuku la o si maa pe  wọn, nitori iwa ọwọ awọn naa ko dara. Ẹyin aṣofin Naijiria, ẹ ronu piwada, ijọba awọn araalu ku si dẹdẹ, to ba de, yoo gbe gbogbo ẹyin aṣebi lọ.

Leave a Reply