Awọn aṣofin wọgi le ilana kawọn aṣoju maa dibo abẹle, wọn fọwọ si gbangba-laṣa-a-ta

Faith Adebọla

Bi Aarẹ Muhammadu Buhari ba fọwọ si abadofin eto idibo ti wọn ṣatunṣe si lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọsẹ yii, a jẹ pe o ti deewọ fawọn ẹgbẹ oṣelu to fẹẹ fa oludije kalẹ lati yan irufẹ oludije bẹẹ pẹlu ilana mi-in ayafi ilana gbangba-laṣa-a-ta nikan, aṣoju ajọ INEC si gbọdọ fọwọ si ilana ati eto idibo abẹle naa.

Ayipada yii waye nigba tawọn aṣofin agba n jiroro lori abadofin eto idibo ti wọn n ṣagbeyẹwo rẹ lọwọ nileegbimọ aṣofin naa, l’Abuja.

Awọn aṣofin naa ti ṣatunṣe si ila kẹtadinlaaadọrun iwe ofin ọhun, eyi to fawọn ẹgbẹ oṣelu lanfaani lati yan oludije labẹ asia ẹgbẹ wọn pẹlu ilana to ba wu wọn, boya ilana ti gbogbo ọmọ ẹgbẹ torukọ wọn wa lakọọlẹ yoo ti dibo abẹle lati yan oludije, iyẹn ilana gbangba-laṣa-a-ta, eyi tawọn eleebo n pe ni Direct Primary, tabi ilana ti awọn aṣoju perete kan yoo ti dibo yan oludije lorukọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ, eyi ti wọn n pe ni Indirect Primary.

Ila kẹtadinlaaadọrun-un naa ka pe: “Ẹgbẹ oṣelu to fẹẹ fa ondije kale fun idibo labẹ abadofin yii gbọdọ tẹle ilana gbangba-laṣa-i-ta lati yan irufẹ ondije bẹẹ fun gbogbo ipo oṣelu, eyi ti ajọ INEC si gbọdọ mojuto.”

Sẹnetọ Ọpẹyẹmi Bamidele lati ipinlẹ Ekiti sọ pe atunṣe lati maa lo ilana gbangba-laṣa-a-ta nikan yii maa ro eto oṣelu demokiresi lagbara, yoo si mu ki ẹnu awọn ọmọ ẹgbẹ tọrọ ninu iyansipo oludije wọn. O lo yẹ ki ilana yii ti bẹrẹ iṣẹ ni Naijiria.

Bakan naa ni Sẹnetọ Adamu Aliero lati ipinlẹ Kebbi sọ pe atunṣe naa maa tubọ mu ki eto iṣelu wa tubọ rẹsẹ walẹ daadaa, yoo si di magomago ku ninu yiyan oludije.

Leave a Reply