Awon aṣofin yari, wọn ni: ‘Buhari, tete sọrọ soke’

Ni ana ode yii, awọn igbimọ apaṣẹ ilẹ wa, iyẹn aarẹ ati awọn minisita rẹ ti wọn jọ n ṣejọba, ṣepade niluu Abuja, Ọgagun Muhammadu Buhjari lo si dari ipade naa. Ṣugbọn ibinu ni ipade naa pada jẹ fawọn eeyan, nitori ninu gbogbo ọrọ ti wọn sọ nibẹ, ati Buhari ati awọn minisita rẹ, ko sẹni kan bayii to mẹnu ba ohun to ṣẹlẹ ni Lẹki,. Eko, nibi ti awọn ṣọja ti yinbọn pa awọn ọdọ ti wọn n ṣewọde jẹjẹ.

Ohun to n ya awọn araalu lẹnu ni bi ilu yoo ti maa gbona to bayii, ti wahala yoo wa kaakiri, ti awọn ọdọ yoo maa fi ehonu han, ti awọn tọọgi yoo maa da ilu ru, ti wọn yoo maa paayan, ti wọn yoo si maa dana sunle ati dukia, ṣugbọn ti awọn ti wọn n paṣe ilu yoo pade lọjọ naa, ti wọn ko si ni wi kinni kan. Bẹẹ gẹlẹ lo si ri, Aarẹ ati awọn eeyan rẹ pade o, ṣugbọn wọn ko wi nkan kan, wọn ko tilẹ ṣe bii ẹni to mọ pe nnkankan  n ṣẹlẹ ni Naijiria.

Bi ọrọ ba ri bayii, awọn eeyan mọ pe ojuṣe olori orilẹ-ede ni lati ba araalu sọrọ, ko fun wọn ni suuru, ki wọn le sinmi agbaja, ki wọn si dawọ ijangbọn duro. Ṣugbọn Buhari ko ba ilu sọrọ lati ọjọ yi, yatọ si ọkan ninu awọn alukoro rẹ to sọrọ, ti awọn eyean si sọ pe kantankantan niyẹn n sọ. Ohun to mu ki ọpọ awọn araalu bẹrẹ si i pariwo pe ki Buhari tete sọrọ soke niyi o.

Awọn aṣofin Naijiria tilẹ ti jade, wọn ni awọn ti paṣẹ tẹlẹ fun Buhari nigba ti ọrọ yii kọkọ bẹrẹ pe ko ba gbogbo ilu sọrọ, ṣugbọn awọn ko mọdi ti ko fi ti i ṣe bẹẹ, wọn waa ni asiko niyi fun un lati tete sọrọ, ko yee fi awọn ọmọ  Naijiria gun lagidi. Ọpọ awọn aṣaaju Naijiria funra wọn ni wọn n lọgun, ohun ti wọn si n wi naa ni pe, ‘Buhari, tete sọrọ soke, ki nnkan too bajẹ patapata o!’

Leave a Reply