Awọn aṣọbode atijọba n fi ayẹwo Korona lu wa ni jibiti ni o – Kunle Afọlayan

Faith Adebọla 

Gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa kan, Ọgbẹni Kunle Afọlayan, ti pariwo pe bii ẹni n lu araalu ni jibiti ni ijọba atawọn ẹṣọ ẹnubode wa n fi kinni naa ṣe, owo kan-n-pa ni wọn n gba lọwọ awọn arinrin-ajo.

Ninu fidio kan to diidi ṣe sori ikanni Instagiraamu rẹ lati kegbajare ọrọ yii, Kunle sọ pe:

“Mo mọ pe fidio yii le ri bakan lara awọn eeyan atawọn alaṣẹ, ṣugbọn mio ri iyẹn ro. Awa kan nifẹẹ orileede yii denu, tori ẹ la o ṣe le gbe ibomi-in, ta a ba rinrin-ajo lọ soke okun fun ọjọ meji mẹta, a tun ti maa sare bọ nile, ajo o le dun bii ile. Bo tilẹ jẹ pe a mọ pe nnkan o lọ bo ṣe yẹ ko lọ nile ọhun, a ṣi gbagbọ pe ti kaluku wa ba ṣa ipa tirẹ bo ṣe yẹ, nnkan ṣi maa daa.

“Iyẹn lo fi jẹ ẹdun ọkan nigba teeyan ba n ri awọn nnkan to wọ, ti o daa, to n ṣẹlẹ, tẹnikẹni ko si ṣe nnkan kan si i, ti aidaa naa si n wa bẹẹ lọ.

“Ijọba paṣẹ pe teeyan ba fẹẹ rinrin-ajo jade kuro lorileede yii, dandan ni ko ṣayẹwo Korona boya o ni in tabi ko ni in, ẹgbẹrun lọna aadọta ati irinwo naira (#50,400) ni wọn n gba funyẹn.

“Teeyan ba si tun fẹẹ pada wale, boya lẹyin ọjọ kan tabi meji teeyan lo lọhun-un, wọn aa tun ni keeyan san owo mi-in, ẹgbẹrun lọna aadọta ati irinwo naira niyẹn naa (#50,400), lati ṣayẹwo Korona. Ki lo de gan-an? Igba wo ni ayẹwo Koro waa di jẹun-jẹun, to jẹ pe teeyan ba fẹẹ rin irinajo ọjọ kan pere jade sorileede mi-in ko pada, afi konitọhun maa mura ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un o lekan silẹ laaye ọtọ.

“Teeyan ba si de awọn ibudo ayẹwo atawọn ọsibitu ti wọn ti fẹẹ ṣayẹwo naa, to o ba bi wọn pe apo ta lowo n lọ, wọn aa ni ijọba ni. Ami ijọba apapọ ati logo ijọba Eko lo si wa lori awọn risiiti ti wọn n ja. Iru jibiti wo niyẹn?

“Emi o mọ o, boya ko si ye mi to ni o, ẹni tọrọ yii ba kan ki wọn ṣalaye ẹ fun wa, eyi n baayan lọkan jẹ gidi, o n dun mi gan-an pe wọn ti tun sọ ayẹwo Koro di okoowo fun ijọba atawọn oṣiṣẹ wọn. “Ṣe eeyan ni lati ge ori ara ẹ lati ṣayẹwo Koro ni? Eyi su mi o, o su mi gidi ni.”

Bẹẹ ni Kunle Afọlayan pariwo.

Leave a Reply