Awọn aṣofin beere boya o kowo jẹ ni o, n lọga ileeṣẹ NDDC ba daku

 

Ọrọ buruku ni, koda o mu ẹrin lọwọ, ṣugbọn awọn ti wọn wa nibẹ ko le rẹrin-in, nitori ọrọ teeyan ko le rẹrin-in si ni. Ileeṣẹ kan wa ti wọn da silẹ fun idagbasoke agbegbe Niger Delta, nibi ti wọn ti n wa epo bẹntiroolu ilẹ wa jade. Niger Delta Development Commission (NDDC) ni wọn n pe ileeṣe ọhun, owo nla nijọba si maa n ko fun wọn lati fi ṣeto idagbasoke agbegbe naa, ṣugbon awọn ọga ileeṣẹ naa a maa ko pupọ ninu owo ibẹ jẹ.

O wa ṣẹlẹ pe wọn ṣẹṣẹ ko awọn owo kan jẹ nibiẹ, owo naa pọ debii pe ko ṣee maa fẹnu royin ni. Ọrọ dun awon aṣofin ilẹ wa, ni wọn ba ni ki awọn ọga ileeṣẹ naa waa ṣe alaye bi ọrọ ti jẹ niwaju wọn, wọn si ni olori ileeṣẹ naa ni ko ṣaaju. Bẹẹ ni Ọjọgbọn Kemebradikumo Pondei ti i ṣe ọga agba pata ni ileeṣẹ naa ṣaaju awọn to ku, ni wọn ba lọọ ba awọn aṣofin lanaa.

Wọn ti wa nibẹ ti wọn n ba ọrọ naa lọ o, afi nigba ti awọn aṣofin bẹrẹ si rọjo ibeere, ti wọn n fẹẹ mọ bi owo to le ni ọgọrin biliọnu ṣe poora lori alejo ṣiṣe ati irin-ajo lasan. Njẹ ki ọgba ileeṣẹ NDDC yii dahun, afi bo ṣe akọ kẹhẹ kẹhẹ lẹẹmeji, lo ba di wọọ nilẹ, ni wọn ba pe e ni ko dahun mọ, ẹran n fẹẹ lọ.

Ni wahala ba ba awọn aṣofin: o ti ku ni ab’o sun ni! Iyẹn naa lo jẹ ki wọn gbe e digbadigba jade. Bẹẹ naa ni iwadii owo kikojẹ naa pari, nitori olori ile igbimọ aṣofin naa, Fẹmi Gbajabiamila ti ni ki wọn ma jẹ kọkunrin naa wa siwaju wọn waa rojọ mọ o. Ṣugbọn awon aṣofin funra wọn ko yee sọrọ naa, pe ṣe ara ọkunrin yii ko ya ni, abi ibeere owo ti wọn ko jẹ nileeṣẹ yii lo mu un daku.

Leave a Reply