Awọn aṣofin Eko buwọ lu eto iṣuna ọdun 2021

Faith Adebọla, Eko

 Ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti buwọ lu tiriliọnu kan, miliọnu mẹtalelọgọjọ naira (#1.163 Trillion) gẹgẹ bii eto iṣuna ipinlẹ Eko lọdun 2021.

Bi Gomina Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ba ti buwọ lu abadofin naa, eyi ni ijọba ipinlẹ Eko yoo lo fun gbogbo inawo ati iṣẹ ilu ti wọn maa ṣe lọdun to n bọ.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lawọn aṣofin ṣagbeyẹwo abadofin ọhun fun igba kẹta lẹyin tawọn igbimọ alabẹ ṣekele ti yẹ ẹ wo finni-finnitu ni isọri-isọri ati lẹka-o-jẹka lati ọsẹ mẹta sẹyin.

Eto isuna ọhun ti wọn pe ni “Ireti Ọtun” ni alaga igbimọ alabẹ ṣekele lori isuna ati inawo, Ọnarebu Gbọlahan Yisawu, to n ṣoju agbegbe Eti-Ọsa ki-in-ni, gbe kalẹ fun agbeyẹwo ikẹyin ati ifọwọsi awọn aṣofin naa.

Olori ile, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, sọ pe ohun to foju han ni pe awọn eto kan bii eto ‘O’YES’ tijọba apapọ gbe kalẹ fun riro awọn ọdọ lagbara lẹka eto ọgbin ko seso rere, ko si sidii lati fowo ilu ṣatilẹyin fun eto ọhun.

Bakan naa lo ni awọn ti dabaa fun gomina lati pa ajọ kan ti wọn pe ni Coconut Agency rẹ, tori ko ṣiṣẹ gidi kan. Ọbasa tun ni awọn ti din owo ti wọn bu fun eto iranwọ lori ẹkọ fawọn akẹkọọ (scholarships), ku, tori ko si alaye to yanju lori bi wọn ṣe nawo ọhun lọdun 2020 yii.

O lawọn aṣofin naa fi kun owo tijọba fẹẹ na lori eto aabo, paapaa fawọn ẹṣọ alaabo Neigbourhood Watch tipinlẹ Eko gbe kalẹ, tori ọrọ aabo ti di nnkan pataki lọwọ yii, awọn si ni lati gba awọn oṣiṣẹ alaabo si i.

Iye tawọn aṣofin fọwọ si yii fi miliọnu mẹjọ le si tiriliọnu kan, miliọnu marun-undinlọgọjọ ti Gomina Sanwo-Olu gbe kalẹ niwaju wọn lọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun yii.

Leave a Reply