Faith Adebọla, Eko
Ofin tuntun kan tile igbimọ aṣofin Eko n po pọ lọwọ bayii maa sọ ọ di dandan fẹnikẹni to ba n sin awọn ẹran ọsin bii aja, ologbo, ọbọ, inaki, ejo ati ẹja akurakuda (sharks) lati gba iwe aṣẹ lọdọ ijọba ki wọn too le ni iru awọn ẹranko bẹẹ nile wọn.
Nibi apero itagbangba kan ti wọn ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, lati gba aba ati ero araalu lori abadofin tuntun naa ni wọn ti sọ eyi di mimọ.
Alaga igbimọ alabẹ ṣekele lori eto ọgbin, Ọnarebu Kẹhinde Joseph, to n ṣoju ijọba ibilẹ Alimọshọ keji, sọ pe abadofin naa maa daabo bo ẹtọ awọn ẹranko ati araalu, yoo si mu ki ofin gidi to maa jẹ ki awọn to n ṣe oṣin awọn ẹranko naa mọ ojuṣe wọn, tori ilu ti ko sofin, ẹṣẹ o si nibẹ.
Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, Olori ile aṣofin ọhun, ẹni ti Igbakeji rẹ, Ọnarebu Wasiu Sanni Ẹshinlokun ṣoju fun, sọ pe asiko ti to lati daabo bo awọn araalu ati awọn ẹran ọsin lọwọ iṣẹkuṣe ati iwa ọdaran. O lawọn ofin to rọ mọ sinsin nnkan ọsin ki i ṣe lorileede yii nikan, ṣugbọn kari aye ni.
Abadofin naa tun ka a leewọ lati polowo tabi ṣe okoowo ẹran ọsin laarin ilu, bii keeyan ko wọn sinu ọmọlanke, tabi baaro (wheel barrow) kaakiri awọn opopona. Owo itanran ẹgbẹrun mẹwaa ni wọn lẹni to ba ṣe iru nnkan bẹẹ maa san nile-ẹjọ tabi ko ṣẹwọn.
Bakan naa ni abadofin ọhun ka a leewọ fẹnikẹni lati sọko lu tabi fi ẹgba na nnkan ọsin, wọn ko si gbọdọ fiya jẹ wọn tabi febi pa wọn, wọn lẹni to ba fẹẹ sin nnkan ọsin gbọdọ ni eto gidi lati bojuto alaafia wọn.
Abadofin naa tun wọgi le pipa ẹranko lai nidii, tabi lọna ika.