Awọn aṣofin Eko ni idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lọna abayọ seto aabo to mẹhẹ

Faith Adebọla, Eko

Latari bi eto aabo ṣe mẹhẹ kaakiri orileede yii, ileegbimọ aṣofin Eko ti sọ pe afi kijọba fọwọ si idasilẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ, ki wọn si fi rọpo awọn ọlọpaa ijọba apapọ ti a n lo lọwọ yii.

Ki eyi le ṣee ṣe, awọn aṣofin naa rọ Aarẹ Muhammadu Buhari ati ileegbimọ aṣofin apapọ lati tete wo bi wọn yoo ṣe ṣagbekalẹ ofin ti yoo faaye gba eto ọlọpaa ipinlẹ.

Olori awọn aṣofin Eko, Ọnarebu Mudashiru Ajayi Ọbasa, lo dabaa ọrọ yii nibi apero wọn to waye lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, l’Alausa, Ikẹja, tawọn aṣofin to wa nikalẹ si panu-pọ fọwọ si i.

Ọbasa ni, “Mo ti ṣakiyesi bawọn eeyan kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii ṣe n beere pe kijọba ṣedasilẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ, aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, naa ti tun ọrọ yii sọ laipẹ yii. Inu mi dun gan-an nigba ti mo ka nipa ẹ ninu awọn iwe iroyin.

“Ọjọ pẹ tileegbimọ aṣofin Eko ti n sọrọ yii, pe ọrọ aabo ilẹ yii o le ri ba a ṣe fẹ lai si awọn ọlọpaa ipinlẹ, a o si ni i dakẹ titi tijọba apapọ maa fi gbe ibeere yii yẹwo, ti wọn si maa tun iwe ofin orileede ṣe lati faaye gba a.

“Loootọ, loṣu diẹ sẹyin, a ṣedasilẹ awọn ẹṣọ alaabo kaakiri awọn ipinlẹ kan, ṣugbọn ọrọ to wa nilẹ yii kọja ọrọ ẹṣọ alaabo.”

Lẹyin tawọn aṣofin ti panu-pọ ti aba naa lẹyin, wọn dari akọwe ile lati kọwe si Aarẹ Buhari lorukọ ileegbimọ aṣofin Eko, ki wọn si fi ẹda abadofin wọn yii pẹlu lẹta naa, ki wọn si kọ iru lẹta ọhun si awọn olori ileegbimọ aṣofin apapo mejeeji, l’Abuja.

Leave a Reply